Àwọn ti ọrọ naa ṣe oju wọn ni ojo arọrọda lo fa
bi afara naa ṣe ja ni Ọjọ Abamẹta.
Eniyan kan ti ku, ti won si n wa eniyan meji
lẹyin ti afara kan ja ni Oko-Erin, Ilorin ni ipinlẹ Kwara.
Àwọn ti ọrọ naa ṣe oju wọn ni ojo arọọrọda lo fa
bi afara naa ṣe ja ni alẹ́ Ọjọ Abamẹta.
Wọn fikun un pe ọkọ ayọkẹlẹ kan n gbe eniyan mẹta
lori afara naa nigba ti o ja, ti wọn si ni awakọ ati awọn eniyan naa ja si
koto, ti wọn ko si le doola ẹmi wọn.
Afara
Loju opo ikansiraẹni ipinlẹ naa ni ijọba ti ni
awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati wa awọn eniyan meji ti wọn n wa naa lawari.
Wọn fikun wi pe igbese ti bẹrẹ lati ri wi pe wọn
dẹkun bi awọn eniyan ṣe n da idọti si oju omi, eleyii to ti fa ki oju odo o kun
ni akunfaya.
Bakan naa ni wọn rọ awọn eniyan lati sọra nipa
kikọ ile si oju omi nipinlẹ naa, eleyii ti wọn ni o sokunfa bi afara naa ṣe ja.
Nibayii, awọn oṣiṣẹ pajawari n ṣiṣẹ lati ri wi pe
wọn tete ri awọn to sọnu náà.
BBC
No comments:
Post a Comment