Kani ki i ṣe pe ijọba ipinlẹ Kwara ko sun asunpara ni, boya aṣiri awọn ti ẹ n wo yii ko ba ma ti tu niru asiko bayii, ṣugbọn nitori pe ijọba ti ko gba igbakugba yii n f'ojoojumọ ṣiṣẹ takuntakun lati ri i pe iwa ajẹbanu d'ohun igbagbe n'ipinlẹ naa lo jẹ ki akara wọn tu s'epo.
Ko din ni ẹgbẹrun kan ati irinwo l'awọn ayederu oṣiṣẹ ti aṣiri wọn ti tu s'ijọba lọwọ wi pe wọn n gba owo oṣu lai ṣiṣẹ, ti wọn si ni iwa naa ko ṣẹyin alaga ẹgbẹ awọn olukọ, NUT ati akọwe agba l'ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri sọrọ awọn olukọ, iyẹn SUBEB.
Laipẹ yii l'aṣiri awọn irinwo tun tu sita wi pe wọn ki i ṣe oṣiṣẹ ijọba, ṣugbọn wọn n gba owo oṣu ijọba loore-koore, eyi to mu ki ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu, EFCC, ẹka t'ilu Ilọrin bẹrẹ iwadii.
Lara awọn aṣiri to tu sita lẹyin t'ọwọ palaba alaga ẹgbẹ awọn olukọ, Salihu Idris Toyin ati akọwe agba l'ẹka ileeṣẹ to n ri sọrọ awọn olukọni, Bayo Audu Onimago lu sita.
Wọn ni obitibiti owo to yẹ ki wọn fi san owo awọn olukọ n'ipinlẹ naa l'awọn eeyan yii ko jẹ. Miliọnu lọna ọgbọn naira ni wọn pe owo naa.
Iwadii ṣi n tẹsiwaju bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan naa ti jẹwọ lori bi wọn ṣe ṣ'apapin awọn owo naa.
Lara awọn ti wọn tun lọwọ si iwa ibajẹ yii ni alakoso eto iṣuna ileeṣẹ SUBEB, Ahmed Husain; oludari ẹgbẹ awọn olukọ, Tijani Idris; oludari eto iṣuna owo ni SUBEB, Ọmọle
John.
No comments:
Post a Comment