Bi wọn ba n tun aye wa, Paul Abam ko tun jẹ b'awọn gbero lati da ṣọọṣi silẹ mọ pẹlu bi aṣiri rẹ ṣe tu n'ibi to ti n ri oogun abẹnugọngọ m'ọlẹ nile onile lati fi ṣiṣẹ iyanu.
Paul Abam ti wọn l'oun ni oludasilẹ ṣọọṣi Word Based Prophetic & Deliverance Ministries ti wọn tun n pe ni City of Deliverance to wa lagbegbe Ugep, ijọba ibilẹ Yakurr, ipinlẹ Cross
River l'ọwọ palaba ẹ segi l'ọjọ Aje, Mọnde to kọja yii.
Ọkan lara awọn aburo rẹ la gbọ pe Paul fẹẹ ri oogun naa mọ ki aṣiri rẹ too tu s'ọwọ awọn ara adugbo.
AWIKONKO gbọ pe ọpọ igba ni Paul ti ri oogun mọ ile ati ayika awọn ọmọ ijọ rẹ ti wọn lowo l'ọwọ daadaa, tabi awọn to ba ni owo l'ọwọ, t'awọn eeyan naa yoo si sare tọ ọ wa fun adura.
Wọn l'awọn to ba wa fun adura ati itusilẹ l'ọdọ Paul lo maa n gba obitibiti owo lọwọ wọn, ti yoo si tẹlẹ wọn lọ sile lati wu oogun naa, eyi ti yoo fi tan wọn pe ẹmi mimọ lo tu aṣiri naa f'oun.
Wọn ni Ororo Iyanu ni Paul maa n ta f'awọn eeyan, ti wọn si ni bi iṣoro onikaluku ba ṣe to ni owo Ororo Iyanu naa yoo ṣe pọ to. Wọn n'igba kan wa ti Paul ta Ororo Iyanu yii fun ẹnikan l'ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin (800,000) naira, to si mu k'awọn eeyan maa sọ oriṣiriṣi.
Ni bayii, b'ọwọ palaba ẹ ṣe segi l'awọn eeyan ti wọn mọ ọn daadaa ti bẹrẹ sii fi ṣẹlẹya kaakiri igboro.
No comments:
Post a Comment