Ọlaide Ọṣinuga, Eko: Bi ile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Ọgba n'ilu Eko ba fi ri i pe ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Chris McDouglas Omosokpea jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, afaimọ ni ko ma fi ẹwọn jura.
Chris McDouglas Omosokpea ni wọn loo ni ṣọọṣi Peculiar Generation Assembly to wa ni ojulẹ kẹtadinlogun si ikọkandinlogun (No.17/19), adugbo Mututiatu Kayọde nitosi adugbo Ayọdele, Mafoluku-Oshodi, Eko.
A gbọ pe ọmọdun mẹrinla kan to jẹ ọmọ ọkan lara awọn to n wa si ṣọọṣi ẹ laṣepọ. O ti to ọdun mẹrin bayii ti wọn ni Chris ti n ba ọmọ naa laṣepọ, ati pe ọmọ naa ti pe ọmọ ọdun mejidinlogun bayii.
Wọn ni Chris gbajumọ daadaa lagbegbe, ati pe Pasitọ Douglas ni wọn maa n pe e pẹlu awọn asọtẹlẹ ati iṣẹ iyanu ti wọn lo maa n ṣe, eyi ti wọn ni ẹmi okunkun wa nibẹ.
Ọmọ naa ni wọn loo gbiyanju lati gba ara rẹ silẹ lọwọ Douglas, ṣugbọn ti wọn ni ko fi silẹ, eyi ti wọn loo mu k'ọmọ naa maa ronu kiri, ti wọn si loo ti pinu lati gba ẹmi ara rẹ.
Awọn ti wọn ti ọrọ bọọ lẹnu lo mu ko jẹwọ nipa bi Douglas ṣe n ko ibasun fun un latigba to ti wa lọmọ ọdun mẹrinla, idi ree ti wọn ṣe lọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, ti wọn si fóju rẹ ba ile-ẹjọ.
Gbogbo akitiyan lati gba beeli Douglas ni kọọtu lo ja si pabo, ti adajọ naa, Onidajọ B. O. Ọṣunsanmi paṣẹ pe ki wọn lọ ti i mọ teṣan ọlọpaa Makinde di ọjọ kẹwaa oṣu keje ọdun yii ti igbẹjọ yoo tun pada waye.
No comments:
Post a Comment