WỌN DÁ ẸJỌ́ IKÚ FÚN AKẸ́KỌ̀Ọ́ TO PA ỌMỌ-ỌDÚN MẸ́TÀLÀ, BẸ́Ẹ̀ NÍ WỌN TÚN KÙ ỌLỌ́PÀÁ SẸ́WỌ̀N ỌDÚN KAN GBÁKO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, May 14, 2020

WỌN DÁ ẸJỌ́ IKÚ FÚN AKẸ́KỌ̀Ọ́ TO PA ỌMỌ-ỌDÚN MẸ́TÀLÀ, BẸ́Ẹ̀ NÍ WỌN TÚN KÙ ỌLỌ́PÀÁ SẸ́WỌ̀N ỌDÚN KAN GBÁKO


Ṣe ni ariwo ẹkún sọ nínú ilé-ẹjọ́ gíga t'ilu Port Harcourt, n'ipinlẹ Rivers nígbà tí wọn dá ẹjọ ikú fún gendekunrin akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ fasiti Port Harcourt kan, Ifeanyi Dike ati Ugochukwu Nwamiro lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn.

Ọmọdébìnrin, ọmọ ọdún mẹ́jọ kan, Victory Chikamso Nmezuwuba la gbọ pé wọn fipá bá laṣepọ, kò tó di pé wọn pá a dànù, tí wọn sì gé ẹ̀ya ara rẹ sí wẹ́wẹ́, ìyẹn lọdun 2017.

Àdúgbo Messiah to wá ní Eliozu, ìlú Port Harcourt n'iṣẹlẹ náà tí wáyé. Dike, ẹni ọdún mẹtalelogun ni wọn loo jí ọmọdébìnrin náà gbé, kí wọn tó pá a dànù. 

Ọwọ àwọn òṣìṣẹ́ fijilante ni wọn loo tẹ àwọn méjèèjì nígbà náà, tí wọn sì fà wọn lé ọlọ́pàá lọ́wọ́. 

AWÍKONKO gbọ pé lásìkò tí wọn ń fọrọ wá Dike lẹ́nu wo lọ́wọ́ ni wọn ní ọkàn lára àwọn ọlọ́pàá tí wọn pé ní Johnbosco Okoronze tuu silẹ láti na pápá bora, ṣùgbọ́n tí wọn padà ríi mu n'ilu Jos, ipinlẹ Plateau lẹ́yìn bí ọsẹ mélòó kan. 

Nígbà tó ń gbé idajọ kalẹ lẹ́yìn ọdún kẹta, Onidajọ Adolphus Enebele sọ pé àwọn ẹ̀rí aridaju lo wá níwájú òun, èyí tó fi hàn wí pé òun pẹ̀lú Chimkamso ni wọn jọ pá ọmọdé bìnrin náà. 

Enebele ni kí wọn lọ yegi fún àwọn méjèèjì, bẹẹ lo tún pàṣẹ wí pé kí ọlọ́pàá tó tuu silẹ lọjọsi, ìyẹn Johnbosco Okoronze náà lọ fi ẹ̀wọ̀n ọdún gbáko gbàrà.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI