WÀHÁLÀ DE! ÀṢÍRÍ ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ TU SÍTA LỌ́NÀ AITỌ, LÀWỌN ỌTẸLẸMUYẸ BA BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ L'ORI ẸNI TO DALẸ̀ ÌJỌBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 26, 2020

WÀHÁLÀ DE! ÀṢÍRÍ ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ TU SÍTA LỌ́NÀ AITỌ, LÀWỌN ỌTẸLẸMUYẸ BA BẸ̀RẸ̀ IṢẸ́ L'ORI ẸNI TO DALẸ̀ ÌJỌBA


Ìjọba àpapọ̀ ni ìwé ìdáró ni òun yóò fún ẹnikẹ́ni tí aje ìwà ìbàjẹ́ gbígbé ìwé àti àṣírí ìjọba síta lórí ayélujára lọ́nà àìtọ́

Ó ní ìwé ìjọba kan tó fara han lórí ayélujára láìpẹ́ yìí níbi tí o ti fi ìwé wa wí tẹnu rẹ sọwọ́ sí akọ̀wé ilé iṣẹ́ àpapọ̀ kan jẹ́ èyí tó tini lójú gidigidi.

Olórí òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ Ọ̀mọ̀wé Folashade Yemi-Esan ló fi ìpè naa síta pé ẹnikẹ́ni tí ìjọba ba mú yóò fẹnu fẹ́ra.

Ìkìlọ̀ yìí kò sẹ̀yìn ìwé ìkìlọ̀ tí wọ́n fun akọ̀wé àgbà ilé iṣẹ́ tó n rí sí ìmọ̀ sáyẹ́nsì Mohammed Bello Umar fún ríra ilé tí wọn ò kọ́ tan ni bilionu méje náírà fún ilé iṣẹ́ to n rí sí ǹkan ọ̀gbìn bo ṣe lu síta lórí ayélujára.

Olórí òṣìṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ ni Umar lo mójú tó ìdúnadúrà naa lásìkò to jẹ́ akọ̀wé ilé iṣẹ́ ǹkan ọ̀gbìn

Bákan naa lo ní akọ̀wé ọ̀un tún gbé iṣẹ́ gbígbẹ́ kànga ìgbàlódé méje síta ni bilionu kan ó lé dí lọ́nà àìtọ́.

Ìdáhùn Umar tó fi ṣọwọ́ padà sí olórí òṣìṣẹ́ níbi tó ti fèsì pé irọ́ pọ́nbélé ni gbogbo ọ̀rọ̀ náà tún jẹ jáde lórí ayélujára bakan náà.

Ọ̀rọ̀ tí Ààrẹ Muhammadu Buhari kà sétí ìgbọ́ ọmọ Nàìjíríà ni ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin lórí ààrùn Covid19 ti ṣáájú Ààrẹ dé orí ayélujára wákàtí díẹ̀ kí Ààrẹ tó dórí afẹ́fẹ́.

Ẹ̀wẹ̀ Yemi-Ẹsan ṣàpèjúwe àwọn ǹkan wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bíi ǹkan to burú jáì lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba tó sì pè fún yíyọ eni ti aje ọ̀rọ̀ náà bá sí mọ́ lórí ní ṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òfin iṣẹ́ ìjọba ṣe gbe kalẹ..

Gbogbo ẹ̀ka ìjọba pátá ní ọ̀rọ̀ naa kàn.

Lati: BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI