Lọ́jọ́ Iṣẹgun, ìyẹn Tuside àná ni Gomina ipinlẹ Èkó, Babajide Sanwo-Olu búra fún àwọn adajọ tuntun tí kò dín ni mẹ́jọ láti lè jẹ ki eto ìdájọ́ n'ipinlẹ náà fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa.
Orí ìkànnì ayélujára tí agbẹyẹfo, ìyẹn Twitter ni Gómìnà Sanwo-Olu tí gbé ọ̀rọ̀ náà síta láti jẹ ki gbogbo àgbáyé mọ nípa rẹ̀ wí pé òun ti búra fáwọn adajọ ilé-ẹjọ́ gíga mẹ́jọ.
Igbesẹ yìí kọ ṣẹyin bí wọn ṣe ni àwọn aláṣẹ lẹka ètò ìdájọ́ orílẹ̀-èdè yìí ni wón bù ọwọ lu àwọn adajọ tuntun náà, kò tó di pé ìjọba Èkó bu ontẹ luu, tí wọn sì búra fún wọn.
Àwọn náà ni: Ọnọrebu Onidajọ Dorcas Taiwo Ọlatokun, Ọnọrebu Onidajọ Yhaqub Gbadebọ Oshoala, Ọnọrebu Onidajọ Ọmọtọla Ibironke Oguntade, Ọnọrebu Onidajọ Olufunkẹ Sule-Amzat, Ọnọrebu Onidajọ Rasul Oriyọmi Olukolu, Ọnọrebu Onidajọ Ṣarafa Abioye Ọlaitan, Ọnọrebu Onidajọ Ezekiel Oluwọle Ashade ati Ọnọrebu Onidajọ Adeniyi Funṣọ Pokanu.
Gómìnà Sanwo-Olu wá a rọ àwọn adajọ tuntun náà láti ṣiṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ, kí wọn sì jẹ ìrètí àwọn mẹkunnu.
Bákan náà ni Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara náà tún búra fáwọn adajọ márùn-ún lónìí, tóun náà sì gba wọn lamọran láti má ṣe ojúsàájú ẹnikẹ́ni.
Àwọn adajọ tuntun náà ni: Funṣọ Dada Lawal, Ọlanipẹkun Ṣẹrifat Bọla, Hussein Toyin Kawu, Nureni Kuranga, ati Umar Zikki Jubril.
No comments:
Post a Comment