Oludije sípò ilé igbimọ aṣofin àgbà nínú idibo ọdún tó kọjá, Ọnọrebu Oluṣẹgun Gbelẹyi tí bá gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí jákèjádò àgbáyé, pàápàá àwọn ará agbegbe Ogun West ṣajọyọ ayẹyẹ ọdún Ìtunu aawẹ Ramadaani.
Ninu atẹjade tí Ọnọrebu Oluṣẹgun Gbelẹyi tó tún jẹ́ oludamọran pàtàkì lórí ọ̀rọ̀ iná mọna-mọna fún Gomina àná, Ibikunle Amosun fi ránṣẹ́ sí AWIKONKO nirọlẹ òní lo tí gbàdúrà pé Ọlọ́run yóò fi àánú gba gbogbo èèyàn.
Ó ní òun dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run tó fáwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí láǹfààní láti gba aawẹ ọgbọ́n ọjọ́ náà yọrí, to sì tún gbàdúrà pé kí Ọlọ́run wo ilẹ̀ Nàìjíríà san kúrò nínú ajakalẹ àrùn gbogbo.
No comments:
Post a Comment