Boroboro làwọn mẹrin kan ń ka ni olú-ileeṣẹ ọlọ́pàá ipinlẹ Ondo tó wà n'ilu Akurẹ ń ka laipẹ yìí nígbà tí àṣírí wọn tú pé ẹ̀ya ara òkú ní wọ́n ń tà fáwọn babaláwo láti fi ṣe aájò owó.
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ, wọn ní àwọn mọlẹbi òkú tí wọn gé orí ẹ ní àṣírí náà tú sí lọ́wọ́, nígbà tí wọn padà lọ sí itẹkuu tí wọn sìn èèyàn wọn sì, tí wọn sì báwọn èèyàn náà níbi tí wọn tí ń gé orí ẹ lọ́wọ́.
AWIKONKO gbọ pé laipẹ yìí làwọn mọlẹbi kan sìn èèyàn wọn sì itẹkuu tó wà nijọba ibilẹ Guusu Akurẹ, tí wọn kò sì tíì fi simẹnti rẹ saare náà.
Won ni kò ju bíi wákàtí mẹ́ta lọ tí lára àwọn mọlẹbi náà padà láti lọ ṣe saare náà dáadáa, kí wọn sì fi simẹnti rẹ orí ẹ, kí àwọn oniṣẹ ibi má bàa raaye láti gbé òkú wọn salọ.
Ìyàlẹ́nu lo jẹ́ pé bí wọn ṣe debẹ, ṣe ni wọn ba àwọn mẹ́rin yìí, tí wọn ń gé orí òkú tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ sìn lọ́wọ́.
Nibẹ ni wọn ti kona ìyá fún wọn, kò tó di pé wọn lọ fà wọn lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ láti fi ẹsẹ òfin tọ ọ.
Nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà mulẹ, agbẹnusọ fáwọn ọlọ́pàá ipinlẹ náà, Tee-Leo Ikoro sọ pé ohun tó ń jẹ kayeefi fáwọn èèyàn ni pé àwọn t'ọwọ palaba wọn segi yìí gan-an ni wọn gbẹn saare òkú yìí laarọ ọjọ́ náà.
Tee-Leo sọ pé "Ni kete ti wọn ke si wa, ni awọn oṣiṣẹ wa lọ si ibẹ, ti a si gba awọn ọdaran naa mu lọrun ọwọ pẹlu ori eeyan ati awọn ẹya ara eeyan miran.
"Ni bayii, a ti bẹrẹ iwadii ni kikun lati mọ boya awọn kan lo ran awọn ọdaran naa niṣẹ tabi iṣẹ ara wọn ni wọn n jẹ."
Agbẹnusọ ọlọpaa naa pari ọrọ rẹ pe awọn afurasi naa yoo foju ba ile ẹjọ lẹyin iwadii.
No comments:
Post a Comment