OHUN TẸNIKẸNI KÒ MỌ NÍPA ÀṢÍRÍ IKÚ TO PA IMAAMU AGBA ILẸ̀ Ẹ̀GBÁ, OLOYE LIADI ỌRUNṢOLU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 26, 2020

OHUN TẸNIKẸNI KÒ MỌ NÍPA ÀṢÍRÍ IKÚ TO PA IMAAMU AGBA ILẸ̀ Ẹ̀GBÁ, OLOYE LIADI ỌRUNṢOLU


Lagboole ẹsin Isilaamu lónìí, odù ni Sheik Liadi Ayinde Ọrunṣolu, ẹni tó jẹ́ Imaamu àgbà fún gbogbo ìlú Ẹ̀gbá nílé-lóko. 

Laarọ òní ọjọ́ Iṣẹgun ni ìròyìn náà deede jáde síta wí pé Oloye Liade Ọrunṣolu tí jáde láyé lẹni ọdún mejidinlọgọrun-un {98}.


Ààrẹ lapapọ fún ẹgbẹ́ àwọn agbarijọ Imaamu àti Aafa nipinlẹ Ogun ni Sheik Ọrunṣolu títí tó fi jáde láyé. 

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó tẹ AWIKONKO lọ́wọ́ laipẹ yìí, wọn loo tí pẹ tí Imaamu Ọrunṣolu tí wá lórí idubulẹ àìsàn ọjọ́ ogbó, tí wọn sì ti gbé káàkiri ọsibitu. 


Àìsàn náà là gbọ pé ó gbà ọ̀nà mi-ín yọ ṣáájú asiko ti Aawẹ Ramadaani ọdún yìí bẹ̀rẹ̀, èyí tí kò jẹ kò fi bẹẹ kópa bíi ti tẹ́lẹ̀.

Nigba ti agbára náà kò gbé e mọ, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ akitiyan àwọn mọlẹbi láti doola ẹmi rẹ là gbọ pé Baba náà tá teru nípa laarọ òní, gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe fi ìròyìn náà tó wà létí. 

Agba Mùsùlùmí tó fi ara jin fún Allah ni Olóògbé Ọrunṣolu nígbà ayé ẹ, tí kò sì fi ọ̀rọ̀ ẹlẹyamẹya ṣe kó too kú. Ipa to kò nìdí ẹsin Isilaamu nínú ètò iṣejọba ìṣàkóso Ibikunle Amosun gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà kò kéré rárá. 


Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ní wón ti ń báwọn mọlẹbi olóògbé náà kẹdun títí di àsìkò yìí, lára wọn sì ni Sẹnetọ Ibikunle Amosun, Gomina Dapọ Abiọdun àtàwọn mi-ín. 

Aago mẹ́rin irọlẹ onii ni wọn yóò sinku bàbà náà n'ilu Abẹ́òkúta nilana ẹsin Isilaamu. Kí Ọlọ́run tẹ ẹ sì afẹ́fẹ́ rere.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI