Yoruba ni oju kii ri arẹwa ko ma kii, oju to ba sì rẹwa, o di
dandan ko pawo wale.
Idi ree ti ọpọ awọn oṣere tiata lobinrin fi n lo ipara ibora
ki wọn lee pupa ni awọ, ti oju wọn yoo si dun wo ninu ere.
Gbajumọ oṣere tiata kan Muka Ray Eyiwunmi lo ṣiṣọ loju ọrọ
yii lasiko to n kopa lori eto kan loju opo ikanni BBC Yoruba.
Muka, ti ọpọ eeyan tun n pe ni Apaṣẹ tiata, tun ṣalaye siwaju
pe, ọpọ awọn oṣere tiata to dudu bíi koro iṣin tẹlẹ ni wọn ti bora, ti wọn si pọn
roboto, ki awọn oṣere lee maa pe wọn lati kopa ninu ere.
"Ọrọ naa wa lọwọ awọn alagbata sinima, awọn Olootu ere atawọn ololufẹ wa, nitori ọmọ pupa ni wọn n wá ninu fiimu ki wọn to wo o, a si maa n fi wọn ta ọja ni amọ awọn ọmọ dudu naa si wa ninu fiimu wa.
Ọpọ onitiata to dudu ti lo di pupa, ki wọn le maa lo wọn ninu ere."
Nigba to n sọrọ lori ajọṣepọ rẹ pẹlu gbajugbaja oṣere tiata
lobinrin kan, Iyabo Ojo, ti ẹnu n kun awọn mejeeji pe ọrọ ifẹ ikọkọ wa laarin wọn;
Muka Ray ni awọn mejeeji jọ n ṣíṣẹ papọ lasan ni amọ araye ro pe awọn n fẹ ara awọn
ni.
"Iyabo Ojo ni iwa irẹlẹ pẹlu oju aanu, yatọ si pe mo jẹ ọga
rẹ, ọrẹ mi ni ninu iṣẹ taa jọ n ṣe. Awọn eeyan ro pe a n fẹ ara wa ni, idi ree
taa fi sun sẹyin funra wa, awọn aye lo tu wa ka."
Lori ipo ti iṣẹ tiata wa:
Apaṣẹ ni "Gbogbo nkan ti bajẹ patapata nítorí ayelujara ni awọn
eeyan ti n wo sinima bayii. Ko si owo ninu iṣẹ tiata mọ,
"Koda, o tun nira lati ni orukọ pẹlu. Akoba ti n wọ iṣẹ tiata
bayii, iṣẹ sinima n ku lọ, sinima ti wọn n wo lori ayelujara ko ni jẹ ki ọpọ
jade lọ wo sinima."
Gbajugbaja oṣere tiata naa, tii ṣe ọmọ agba ọjẹ oṣere to ti
di oloogbe, Ray Eyiwunmi, tun kede fun araye pe, inu ẹjẹ oun ati awọn ẹgbọn oun
ni iṣẹ tiata wa, ogun nla tí baba awọn si fi silẹ fun awọn nìyẹn.
O ni oun ati awọn ẹgbọn oun ni awọn jọ jogun iwe akọsilẹ
ere ti baba awọn fi silẹ, owo nla ti awọn ere naa si nilo ni ko tii jẹ ki awọn
gbe sinima rẹ jade.
Muka Ray wa rọ ijọba Naijiria lati maa ṣeto iranwọ, nipa
amulo awọn dukia ijọba pẹlu owoya, fun awọn oṣere tiata, eyi ti yoo mu ko rọrun
fun wọn lati ṣe eré to ni èrè, ti yoo si pawo gidi wọle fun ijọba.
Bakan naa lo tun rọ awọn akẹẹgbẹ rẹ ninu iṣẹ tiata, lati maa
pe awọn agba ọjẹ oṣere to ti darugbo si iṣẹ, eyi ti yoo mu ki ẹmi wọn gun, ti
gbogbo aye yoo si tun mọ pe wọn wa laaye, ti wọn ko si ni jẹ ohun elo alopati.
BBC
No comments:
Post a Comment