Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun tí so pé kò sí nnkan tòun tún lè ṣe láti lè tètè jẹ́ kí àrùn aṣekupani Covid-19 kasẹ nilẹ bí kò ṣe pé koun tún fi ọ̀sẹ̀ kan gbáko kún konile-o-gbele tó ń lọ lọ́wọ́ yìí.
Lónìí ní Gomina Abiọdun sọ̀rọ̀ náà lásìkò tó ń báwọn akọroyin n'ipinlẹ Ogun sọ̀rọ̀ ni ọfiisi rẹ tó wà ní Oke-Mọsan, Abẹ́òkúta.
O sọ pe nígbà tòun sọ̀rọ̀ gbẹ̀yìn nípa àrùn koronafairọọsi, pàápàá ti konile-o-gbele, ọgọ́rùn-ún kan làwọn tó ti ní àrùn náà lára, ṣùgbọ́n nígbà tí yóò fi di ọjọ́ Tọside àná, àwọn tó ti ní àrùn náà tí lè ní mẹrinlelọgbọn ni ọgọ́rùn-ún kan {134} láàárín ọ̀sẹ̀ kan.
Gómìnà fi kún ọ̀rọ̀ rẹ wí pé ojoojumọ làwọn ṣàyẹ̀wò fáwọn aráàlú, tó sì jẹ pe àwọn tí kò dín ni irínwó àti àádọ́ta {450} làwọn ń yẹwo lojumọ, táwọn sì tún ti fi kún agbára àwọn òṣìṣẹ́ láti tẹsiwaju.
Ọ ní lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ikilọ ìjọba àtàwọn agbófinró nípa isunmọra-ẹni, ìyẹn Social distancing, síbẹ̀ ó làwọn aráàlú ṣí ń sunmọ ara wọn gidigidi, pàápàá láàárín ọjà.
Dapọ Abiọdun làwọn aráàlú lo ṣí ń jáde lai lo ibomu, táwọn ọlọkada ń gbé ju èrò kan lọ, táwọn awakọ taisi náà sì ń gbé ju èrò mẹ́ta lọ.
Bákan náà lo ni àwọn ọgọ́rùn-ún kan lè ní mẹ́jọ làwọn tọwọ tí tẹ, tí wọn lugbadi òfin konile-o-gbele àti isunmọra-ẹni, tí wọn sì ti fojú bá ilé ẹjọ. Bẹ́ẹ̀ lo ni àwọn mọto ẹẹdẹgbẹta lè ní mẹtadilogun {517} làwọn ọlọ́pàá tí gba, tí wọn sì ti gbà ọkada ọgọ́rùn-ún lè ní mẹ́sàn-án {109}, to fi mọ kẹkẹ maruwa mẹ́fà.
O ni gbogbo èyí kò lè jẹ ki àrùn náà tètè kasẹ nilẹ báwọn ṣe ń fẹ́, ìdí re e tó fi lòun yóò fi ọ̀sẹ̀ kan gbáko kún-un.
Lákòótán, ó ní ìjáde ṣí wá bíi ti tẹ́lẹ̀, ìyẹn lọ́jọ́ Mọnde, Wẹside àti Fraide láàárín aago méje sì márùn-ún irọlẹ títí di ọjọ Àìkú, Sande, ọjọ́ kẹrinlelogun.
No comments:
Post a Comment