NÍTORÍ AARUN KORONAFAIRỌỌSI, WÀHÁLÀ ŃLÁ TUNTUN BẸ̀RẸ̀ LÁÀÁRÍN ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ APC ÀTI PDP NÍ KWARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, May 2, 2020

NÍTORÍ AARUN KORONAFAIRỌỌSI, WÀHÁLÀ ŃLÁ TUNTUN BẸ̀RẸ̀ LÁÀÁRÍN ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ APC ÀTI PDP NÍ KWARA


Kí í ṣe ọ̀rọ̀ ahesọ wí pé bi ọ̀rọ̀ ata àti ojú ni ẹgbẹ́ òṣèlú PDP àti APC káàkiri orílẹ̀ èdè yìí fi mú ara wọn, táwọn méjèèjì sì ń fi ojoojumọ wá ẹ̀sùn sì ara wọn l'ẹsẹ. 

Látìgbà tí aarun aṣekupani Covid-19 tí wọ Nàìjíríà, làwọn èèyàn káàkiri tí bẹ̀rẹ̀ si í ṣe iranwọ fáwọn tó kú díẹ̀ kaato fún láwùjọ, kò dá, táwọn ìjọba ipinlẹ náà kò gbẹyin láti máa fáwọn aráàlú lounjẹ, pàápàá bijọba àpapọ̀ ṣe kéde konilegbele fún gbogbo èèyàn.

Lára àwọn ipinlẹ tí wọn ń ṣe iranlọwọ owó àti oúnjẹ fáwọn èèyàn wọn ní ipinlẹ Kwara tí Malaamu AbdulRahman AbdulRazaq jẹ́ gómìnà wọn. 

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni wọn fẹ̀sùn kan ìjọba ipinlẹ náà laipẹ yìí wí pé ẹlẹyamẹya ni wọn ń ṣe lórí àwọn nǹkan tí wọn ń pín fáwọn aráàlú, nítorí pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC nìkan ni wọn ń fún lounjẹ àti owó iranwọ konilegbele. 

Bí ẹ̀sùn náà ṣe jáde síta ni Alaaji Tajudeen Fọlaranmi Aro to jẹ́ akọwe ìpolongo ẹgbẹ́ APC tí pariwo síta wí pé kò sí òótọ́ kankan nínú ọ̀rọ̀ tí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ń gbé káàkiri pé ojúsàájú ni wọn fi ń pín nnkan fáwọn aráàlú Kwara. 

Alaaji Aro sọ pé kí í ṣe àsìkò tó yẹ káwọn ẹlẹyinju àánú dìde láti rán àwọn èèyàn lọ́wọ́ lásìkò konilegbele yìí, àti pé asiko tó yẹ kí ẹgbẹ́ PDP máa wà irẹpọ àti ìṣọ̀kan lo jẹ́ pé wàhálà ni wọn ń dá silẹ. 

Bẹẹ lo tún sọ pé aarun Covid-19 tó ń dá gbogbo àgbáyé láàmú kò mọ olówó, mẹkunnu àti olóṣèlú, nítorí náà lo ṣe jẹ́ pé ọ̀nà àbáyọ láti dẹ́kun aarun náà lo yẹ kí wọn máa wa á dípò ọ̀rọ̀ tó dé là wàhálà silẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI