MAY 29! GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ FẸẸ B'ÀWỌN ARÁÀLÚ SỌ̀RỌ̀ L'ORI ÌBÍ ABAṢẸDE, AAGO MỌKANLA ÒWÚRỌ̀ YÌÍ NI O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, May 29, 2020

MAY 29! GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ FẸẸ B'ÀWỌN ARÁÀLÚ SỌ̀RỌ̀ L'ORI ÌBÍ ABAṢẸDE, AAGO MỌKANLA ÒWÚRỌ̀ YÌÍ NI O


Ni kété tí ìròyìn náà jáde síta, láwọn ọmọ àti olùgbé ipinlẹ Kwara jákèjádò àgbáyé tí bẹ̀rẹ̀ sii fi ọ̀rọ̀ ìkíni àti idupẹ ranṣẹ sì Gómìnà sí Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq tó là ojú wọn sì igbe ayé tuntun. 

Ìyàlẹ́nu ńlá lo jẹ́ pé lásìkò taa ṣakojọpọ ìròyìn yìí tán, kò dín ni ẹgbẹ̀rún márùn-ún atẹjiṣẹ idupẹ, àdúrà àti ìmọ-rírì lo tí wọlé sórí nọ́mbà t'ijọba gbé síta láti béèrè ìbéèrè. 

Lónìí ní Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq yóò bá gbogbo àwọn ọmọ àti olùgbé ipinlẹ Kwara pátápátá sọ̀rọ̀, níbi tí yóò ti máa dúpẹ́ fún ifọwọsowọpọ wọn, àti ibi tí iṣẹ de dúró láàárín ọdún kan tó gbà ipò láti sìn wọ́n. 

Nibẹ làwọn aráàlú náà yóò ti láǹfààní láti béèrè oríṣiríṣi ìbéèrè tó bá ń rú wọn lójú, tí wọn yóò sì tún gbà gómìnà nimọran. Èyí tí a gbọ pé irú rẹ kò tíì ṣẹlẹ̀ rí. 

Aago mọ́kànlá òwúrò yìí ni eto naa yoo bẹ̀rẹ̀ lórí àwọn ìkànnì rédíò tó wà káàkiri ipinlẹ náà. 

Àwọn ileeṣẹ rédíò náà ni:

1. Midland FM 99.1 
2. Radio Kwara AM (612 kilohertz) 
3. Harmony FM 103.5 
4. Royal FM 95.1 
5. Sobi FM 101.9
6. TNT Ijagbo 102.5
7. OFM 92.5 
8. Igbomina Radio 90.9FM
9. Albarka FM 89.9
10. Unilorin FM 89.3 
11. Gravity FM 97.2

F'awọn to bá fẹ́ ẹ béèrè ìbéèrè tàbí wọn ní ọ̀rọ̀ láti sọ, nọ́mbà kan ṣoṣo yìí, 09018254999 ni wọn yóò fi atẹjiṣẹ ranṣẹ sì, lórí ìkànnì WhatsApp lásán sì ni.

Láàárín asiko yii si aago mẹ́jọ ni wọn yóò fi gba atẹjiṣẹ náà wọlé. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI