Alábòójútó ileeṣẹ Skyscream Global Concept to ń ṣe popona, Onímọ̀-ẹ̀rọ Timothy Adekẹyẹ tí sọ pé òpópónà Esie Museum n'ipinlẹ Kwara yóò parí laipẹ.
Bẹ ó bá gbàgbé, gbedeke ọjọ́ tí wọn ṣadehun òpópónà yìí lọ́jọ́ kẹrindinlọgbọn oṣù yìí.
Òpópónà yìí gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ ti kọjá ìdajì, tí kò sì ní pẹ ẹ parí.
Díẹ̀ re e lára àwọn àwòrán òpópónà náà níbi tí iṣẹ de dúró:
Nínú ìròyìn mi-in tó tún fi ara pẹ àkànṣe iṣẹ tó ń lọ lọ́wọ́ káàkiri ipinlẹ náà là tún ti gbọ pé ìjọba tí parí àtúnṣe lórí àwọn ibùdó tí wọn tí ń gbé omi jáde.
Lára àwọn ibùdó omi náà ni: Asa Dam (Central); Patigi (North); Gwanara (North); Lafiagi (North); àti Igbaja (South).
Bákan náà ni wọn yóò tún parí ibùdó omi tí Yashikira lọ́jọ́ kọkandinlọgbọn oṣù yìí.
No comments:
Post a Comment