KORONAFAIRỌỌSI PA ÈÈYÀN MÉJE L'OGUN ÀTI KANO, BẸ́Ẹ̀ L'ARUN NÁÀ TÚN PA ÈÈYÀN AKỌKỌ NÍ KWARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, May 9, 2020

KORONAFAIRỌỌSI PA ÈÈYÀN MÉJE L'OGUN ÀTI KANO, BẸ́Ẹ̀ L'ARUN NÁÀ TÚN PA ÈÈYÀN AKỌKỌ NÍ KWARA



Coronavirus in Nigeria: Covid-19 ṣekúpa èèyàn méje lọ́jọ́ kan ní Kano àti Ogun. 

Aarun coronavirus tun ti ṣekupa eeyan meje nipinlẹ Kano ati ipinlẹ Ogun.
Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun ni Naijiria lo fidi iroyin yii mulẹ ninu atẹjade kan fi wọn fi lede loju opo Twitter wọn.
Eeyan marun un ninu awọn meje ọhun lo ku ni ipinlẹ Kano nigba ti meji ku ni ipinlẹ Ogun.
Bakan naa ni covid-19 sọ eeyan kọọkan di oloogbe nipinlẹ Bauchi, Kaduna ati Sokoto.
Awọn eeyan mẹwaa yii lo jẹ Ọlọrun nipe lọjọ Ẹti lẹyin ti lugbadi coronavirus.
Eyi lo jẹ ji gbogbo awọn ti coronavirus ti ṣekupa bayii ni Naijiria jẹ mẹtadinlọgọfa.
Ipinlẹ Eko ti eeyan mẹtalelọgbọn ti di oloogbe ni aarun covid-19 ti pawan julọ ni Naijiria.

Social embed from twitter

386 new cases of ;

176-Lagos
65-Kano
31-Katsina
20-FCT
17-Borno
15-Bauchi
14-Nasarawa
13-Ogun
10-Plateau
4-Oyo
4-Sokoto
4-Rivers
3-Kaduna
2-Edo
2-Ebonyi
2-Ondo
1-Enugu
1-Imo
1-Gombe
1-Osun

3912 cases of in Nigeria
Discharged: 679
Deaths: 117


View image on Twitter
Lati: BBC

Aláìsàn àkọ́kọ́ kú ní Kwara - Ajakaye
Akọwe Gomina ipinlẹ Kwara, Rafiu Ajakaye tí fìdí rẹ múlẹ̀ laipẹ yìí pé èèyàn kan náà tí kú lónìí n'ipinlẹ náà, tó sì jẹ pe àyẹ̀wò tí fìdí rẹ múlẹ̀ pé àrùn aṣekupani, Covid-19 lo pa a. 

Rafiu Ajakaye to tún jẹ́ agbẹnusọ fún àjọ tó ń rí sọ̀rọ̀ ìpolongo àrùn náà lo sọ̀rọ̀ yìí lónìí, kí tó sì ni ilu Eko ni ẹni náà tí wá pẹ̀lú ìyàwó àti ọmọ rẹ kan. 

O ni àìsàn rọpa-rọsẹ lo ṣe ẹni náà n'ilu Eko kò tó di pé wọn gbé e wá sílè fún ìtọ́jú, tó sì jẹ pe àárọ̀ òní, Satide lo dagbere fáyé, tí àyẹ̀wò sì jẹ kò di mimọ àrùn Covid-19 lo rán án lọ sọrun. 

Ajakaye làwọn tí kò ìyàwó àti ọmọ olóògbé náà lọ sí ibùdó ayẹwo, táwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ láti wá àwọn tí olóògbé náà ni ibaṣepọ pẹ̀lú kò tó o kú.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI