Aarẹ orile-ede South Africa, Cyril Ramaphosa sọ pe bẹrẹ lati ọjọ
kinni, osu Kẹfa lawọn ile ijọsin yoo bẹrẹ isin pada sugbọn awọn ilana yoo wa
lati ri pe awọn dẹkun itankalẹ arun Covid-19 nibẹ.
Sọọsi, Mọsalasi, Tẹmpili ati awọn ile ijọsin miran yoo ni
lati tẹle ilana itakete-sira-ẹni fawọn olujọsin.
Eeyan aadọta pere tabi to kere ju bẹẹ lọ ni wọn yoo faaye gba
lati kopa ninu ijọsin lawọn aaye wọnyi.
Gbogbo awọn olujọsin si ni yoo ni lati lo ibomu pẹlu ọsẹ ifọwọ
toloyinbo n pe ni hand sanitizer.
Aarẹ Ramaphosa ni oun ko ko iyan awọn olori ẹlẹsin kere nipasẹ
ipa ti wọn n ko ninu adura sise ati idanilẹkọọ.
O sọ pe Covid-19 ti lapa lara bi awọn ti se n se ijọsin tẹlẹ
ati pe nkan to mu ki oun faaye gba ki wọn si awọn ile ijọsin pada ni yẹn.
O tun wa kede ọjọ kọkanlelọgbọn, osu Karun un, gẹgẹ bi ọjọ
adura alapapọ lorile-ede naa.
Saaju lawọn olori ẹlẹsin kan ti sun ọpọn ijọsin wọn lọ si oju
opo ayelujara lẹyin ti ijọba kede titi awọn Mọsalasi ati Sọọsi pa ni osu Kẹta ọdun
yii nitori itankalẹ coronavirus.
Ni bayi eeyan ẹgbẹrun mẹrinlelogun le diẹ lo ti lugbadi arun
naa.
Iye yi ni ẹyi to pọju lọ nilẹ Afrika.
BBC
BBC
No comments:
Post a Comment