Ààrẹ Muhammadu Buhari tí sọ pé ìjọba Nàìjíríà tí ṣetan láti ra oògùn tí ìjọba orílẹ̀-èdè Madagascar ń polówó rẹ káàkiri. Oògùn náà ni wọ́n sọ pé ó lè gbógun ti aarun aṣekupani Covid-19 lára ni kíákíá.
Boss Mustapha to jẹ́ akọwe ìjọba àti alaga igbimọ COVID-19 ni Nàìjíríà lo gba ẹnu Ààrẹ Buhari sọ̀rọ̀ lónìí ọjọ́ Aje, Mọnde lásìkò tó ń báwọn oniroyin sọ̀rọ̀ wí pé àwọn tí ṣetan láti dán oògùn náà wò.
O ni àwọn tí bẹ̀rẹ̀ igbesẹ láti lọ kò àwọn oògùn nítorí pé àwọn gbọ́dọ̀ ṣàyẹ̀wò rẹ, kò too di pé ó dé orí ìgbà àwọn tó ń tà oògùn òyìnbó, ìyẹn Pharmacy.
AWÍKONKO gbọ pé àwọn orílẹ̀-èdè bíi Equatorial Guinea, Guinea-Bissau, Niger, ati Tanzania ni wọn ti rà oògùn yìí lọ́wọ́ Madagascar.
No comments:
Post a Comment