Àgbà oṣere tíátà tó tún jẹ́ adẹrinpoṣonu nnì, Jerry Stiller ti jáde láyé lẹni ọdún mejilelaadọrun-un {92}.
Odu ni Jerry Stiller, kíi ṣaimọ f'oloko nìdí iṣẹ tíátà, pàápàá láwùjọ àwọn oṣere alawada nilẹ Amẹ́ríkà, ẹni tó di olókìkí nínú fíìmù Broadway àti Seinfeld.
Ọmọ Jerry, ìyẹn Ben Stiller lo gbé ìròyìn ikú bàbà rẹ síta laarọ òní, Mọnde
Stiller àti ìyàwó rẹ, Anne Meara ni wọn jọ ń kopa sinima lọ́dún 1960s, tó sì gba oríṣiríṣi aami ẹyẹ kò tó o ku.
No comments:
Post a Comment