Ìyàlẹ́nu ńlá gba a lo ṣí ń jẹ fún pupọ àwọn èèyàn, pàápàá àwọn ọmọ ipinlẹ Kwara nígbà tí wọn rí Gomina wọn, AbdulRahman AbdulRazaq níbi tó ti ń gba idanilẹkọọ nípa imọ ìjìnlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ẹrọ ayélujára lónìí ọjọ́ Satide.
Eto idanilẹkọọ tí wọn pé ní K-Power t'ijọba ipinlẹ Kwara, ileeṣẹ Google àti àjọ Wootlab ṣagbatẹru rẹ lo tí bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ Tọside ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí, níbi táwọn ọdọ tí ko dín ni ẹgbẹ̀rún mẹ́ta {3,195} tí kópa.
Ọna láti jẹ káwọn ará ipinlẹ náà, pàápàá àwọn ọdọ lè gbà ẹgbẹ́ pé lagbaye lo mú kijọba lo àǹfààní konile-o-gbele yìí láti ṣe idanilẹkọọ ìgbàlódé náà.
Gómìnà AbdulRazaq nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lónìí lórí eto naa sọ pé bí gbogbo àwọn òṣìṣẹ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn ileeṣẹ ṣe wá ní títì pá yìí, dandan ni ki iṣẹ tẹsiwaju.
O ni ó ṣeé ṣe kó jẹ pe eto yìí ni yóò jẹ káwọn òṣìṣẹ́ padà sẹnu iṣẹ wọn, àti pé kii ṣe dandan kí wọn fojú kojú kò tó o di pé wọn ṣíṣẹ papọ.
Bẹẹ lo sọ pé ó ṣe pàtàkì fáwọn òṣìṣẹ́ láti lè lo àwọn irinṣẹ ẹ̀rọ ìgbàlódé yìí láti máa fi ṣíṣẹ láti ilé wọn lai jẹ pe wọn lọ sibiṣẹ.
No comments:
Post a Comment