Gbogbo àwọn tí wọn gbọ nípa iyaale ilé ẹni ọdún méjìdínlógún nnì, Salman Hassan lo ń ṣe ní kayeefi lórí bo ṣe fibinu gùn ọkọ rẹ pá lẹ́yìn ọjọ́ mọ́kànlá tí wọn ṣe ìgbéyàwó.
Ìpínlẹ̀ Bauchi niṣẹlẹ náà tí wáyé lọ́jọ́ kẹrìnlelogun oṣù kẹrin ọdún yìí.
AWIKONKO gbọ pé Salman àti ọkọ rẹ tó ti doloogbe, Mohammed Mustapha nífẹ̀ẹ́ ara wọn gidigidi, tí wọn sì ni ọkọ náà fẹ́ràn ibalopọ, èyí tí wọn ní kó bá Salman lára mú pupọ.
A gbọ pé ṣe ni Mustapha lọ bá Salman níbi tó wà, tó sì ni kò jẹ káwọn jọ gbádùn ara wọn gẹ́gẹ́ bí l'ọkọ-l'aya. Wọn ní ṣe ni Salman sọ pé ara òun kò sì lọ́nà.
Ere ni Mustapha pé ọ̀rọ̀ náà, ó ìdí ree tó fi bere sii bàa ṣeré tipátipá. Nibẹ ni wọn ní Salman tí lọ fà ọbẹ yọ, tó sì fi gún ọkọ rẹ l'ọkan.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Salman sọ pé "A nífẹ̀ẹ́ ara wa gan-an. Ọjọ mọ́kànlá lẹ́yìn tí a ṣe ìgbéyàwó lo wá bá mi láti lajọṣepọ, mi ò gbà fún un. Ó gbà mí, ìbínú yìí ló jẹ́ kí n lọ fà ọbẹ yọ láti fi dẹru bàa.
"Mi ó mọ pe ọbẹ náà máa paa. Inú wàhálà ńlá ni mo kò sì yìí, Ibanujẹ ńlá lo ń jẹ fún mi báyìí. Mí ó mọ nnkan tó lè ṣẹlẹ̀ sí mi níbi tí mo wà yìí."
Kọmiṣanna ọlọ́pàá ipinlẹ náà, Philip Maku sọ pé ọsibitu jẹnẹra tí Itas-Gadau ni wọn ti fìdí rẹ múlẹ̀ wí pé Mohammed tí kú, tó sì làwọn kò ní pẹẹ fojú Salman bá ilé ẹjọ́.
No comments:
Post a Comment