Bí ẹgbẹ òṣèlú PDP kò bá tètè wá nnkan ṣe sí ọ̀rọ̀ wàhálà tuntun tó lè dá ogún abẹle silẹ láàrin wọn lásìkò yìí, afaimọ kò má jẹ́ pé ẹgbẹ́ náà yóò tuka pátápátá kí idibo ọdún 2023 too de.
Lọ́jọ́ Ẹtì, ìyẹn Fraide àná làwọn igun kan nínú ọmọ ẹgbẹ́ Peoples Democratic Party, PDP, that ẹ̀ka t'ipinlẹ Ogun tí wọn jẹ ti Sẹnetọ Buruji Kaṣamu làwọn gbé eto idibo kalẹ, níbi tí wọn tí yàn àwọn adarí tuntun tí yóò tukọ ẹgbẹ́ náà fún ọdún mẹ́rin mi in.
Bí ìròyìn náà ṣe tẹ àwọn aṣiwaju ẹgbẹ́ náà n'ilu Abuja lọ́wọ́ ni wọn ti bẹ̀rẹ̀ si í sọ pé kò lè rí bẹ́ẹ̀, kò gbọ́dọ̀ jẹ́ bẹẹ, ṣùgbọ́n táwọn ìwé ìròyìn gbé e loriṣiriṣi, tó fi mọ AWÍKONKO wá yìí.
Ṣáájú àsìkò yìí ni alaga ẹgbẹ́ náà, Olóyè Bayọ Dayọ tí sáà rẹ pari nínú oṣù kẹrin tó kọjá yìí tí sọ pé kò sẹni tó lè yọ òun gẹ́gẹ́ bí alaga, àyàfi bí àṣẹ bá wà láti òkè, tàbí tí idibo gbogboogbo bá wáyé.
Bẹẹ lo tún sọ pé àwọn aṣiwaju ẹgbẹ́ náà tí pá a láṣẹ wí pé káwọn oloye tí sáà wọn tí parí ṣí máa tẹsiwaju dìgbà tí àrùn aṣekupani Covid-19 yóò fi kasẹ nílẹ̀ pátápátá, tí wọn yóò sì gbé eto ìdìbò láti yan àwọn olóyè mí ín kalẹ.
Nínú atẹjade tí alaga àti akọwe ẹgbẹ́ náà n'ilu Abuja, Uche Secondus àti Sẹnetọ Umaru Tsauri jọ t'ọwọ bọ lónìí ní wọn tí sọ pé idibo kan tí wọn ṣe n'ipinlẹ Ogun kò lẹsẹ nílẹ̀ nítorí pé asiko idibo ẹgbẹ́ kò tíì tó.
O ni bí àsìkò idibo bá tó, gbogbo agbaye ni yóò mọ nípa rẹ, kí í ṣe pé káwọn kan kò ara wọn jọ láti gbe eto idibo awuruju kalẹ, kí wọn sì lè máa fi tán ara wọn àtàwọn alaimọkan jẹ.
Nínú atẹjade náà lo tun tí fìdí rẹ múlẹ̀ pé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kan ṣoṣo lo wá, tí wọn sì ni Olú-ileeṣẹ wọn ní Wadata Plaza, Plot 1970, Micheal Okpara Street Wuse Zone 5, Abuja.
O wa a rọ àwọn èèyàn wí pé kí wọn yàgò fáwọn nnkan tó lè dá àlàáfíà ìlú láàmú, tó sì ṣeé ṣe kó jẹ ìpalára fún wọn, àti pé idibo kankan kò wáyé rárá bí kò ṣe pé àwọn tó fẹẹ dá ẹgbẹ́ náà ru lo wá nìdí ẹ.
No comments:
Post a Comment