GANDUJE, ÀTÀWỌN GÓMÌNÀ ILẸ̀ HAÚSÁ WỌ WÀHÁLÀ TUNTUN L'ORI ÀDÚRÀ ÌTUNU AAWẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 26, 2020

GANDUJE, ÀTÀWỌN GÓMÌNÀ ILẸ̀ HAÚSÁ WỌ WÀHÁLÀ TUNTUN L'ORI ÀDÚRÀ ÌTUNU AAWẸ


Ìdààmú ńlá tuntun lo tún de ba gbogbo àwọn gómìnà ilẹ̀ Hausa báyìí, lórí bí àjọ kan tó ń jà fún ẹsin Mùsùlùmí, ìyẹn Muslim Rights Concern (MURIC) ṣe pàrọwà sí Ààrẹ Muhammadu Buhari láti fìyà jẹ àwọn gómìnà yìí lábẹ́ òfin. 

Kii ṣe pé àjọ náà dee de pé ìjọba àpapọ̀, pàápàá Ààrẹ Buhari láti fi iya tó tọ́ jẹ́ àwọn gómìnà yìí, bí kò ṣe ẹ̀sùn tó fi kan wọn wí pé wọn tàpá sì òfin konilegbele, àti pàápàá bijọba àpapọ̀ ṣe pàṣẹ wí pé káwọn ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí jákèjádò Nàìjíríà gbàdúrà nínú ilé wọn. 

Ìjọba àpapọ̀ àtàwọn aṣáájú ẹsin nínú Isilaamu bíi Jamaatu Nasril Islam (JNI) ati Nigerian Supreme Council for Islamic Affairs (NSCIA) tí sọ pé kí gbogbo àwọn Mùsùlùmí gbàdúrà ìparí aawẹ Ramadaani nínú ilé wọn, tí wọn sì tún ṣe idanilẹkọọ lórí ọ̀nà tí wọn yóò gbà ṣe àdúrà náà. 

Èyí ni lati le dẹkun itankalẹ ajakalẹ àrùn COVID-19, ìyẹn Koronafairọọsi to ń dá àgbáyé riboribo. 

Ìyàlẹ́nu lo jẹ́ pé ṣe làwọn èèyàn tàpá sì àwọn òfin àti àṣẹ ìjọba làwọn ilẹ̀ Hausa bíi Kano, Borno, Nasarawa, Jigawa àtàwọn mi-in, tí wọn sì lọ kirun pẹlu ipejọpọ rẹpẹtẹ. 

Ninu atẹjade tí Alakoso ẹgbẹ́ MURIC, Ọjọgbọn Ishaq Akintọla fi ranṣẹ sì Ààrẹ Buhari lo yí sọ pé afi káwọn gomina tó tàpá sì òfin yìí jìyà ẹṣẹ wọn, nítorí pé kò sẹni tó kọjá òfin. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI