ÈYÍ NI B'ÀWỌN FIJILANTE ṢE KÒ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ KỌSITỌỌMU YỌ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ONIFAYAWỌ TO FẸẸ DA SERIA FUN WỌN L'ABẸOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 19, 2020

ÈYÍ NI B'ÀWỌN FIJILANTE ṢE KÒ ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ KỌSITỌỌMU YỌ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ONIFAYAWỌ TO FẸẸ DA SERIA FUN WỌN L'ABẸOKUTA


Bọsun Ọlaniyi: Kani kí i ṣe pé àwọn òṣìṣẹ́ alaabo ojulalakanfinṣọri, ìyẹn fijilante kò tètè de agbègbè Òkè-Ṣokori n'ilu Abẹ́òkúta ni, ó ṣeé ṣe kí wàhálà ńlá tí ṣẹlẹ̀ lónìí.

Ohun tí a gbọ ni pé àwọn òṣìṣẹ́ aṣọbode, kọsitọọmu ni wọn lé àwọn onifayawọ de ilu Abẹ́òkúta lọsan òní, Tuside, tó sì kú díẹ̀ kí wọn kọjú ìjà sí ara wọn.

A gbọ pé mọto àwọn onifayawọ mẹ́ta làwọn kọsitọọmu lè dé agbegbe Òkè-Ṣokori, níbi tí wọn làwọn onifayawọ náà tí pé àwọn èèyàn wọn láti kọjú ìjà wọn.

Lára àwọn t'iṣẹlẹ náà ṣojú wọn, tí wọn ba AWIKONKO sọ̀rọ̀ fi ye wá pé báwọn kọsitọọmu náà ṣe de agbègbè yìí làwọn onifayawọ tí rògbà yí wọn ká, tí wọn sì bẹ̀rẹ̀ sii bá wọn fà wàhálà. 

Àwọn òṣìṣẹ́ fijilante ìyẹn VGN tí wọn wá nítòsí là gbọ́ pé wọn sáré de bẹ láti gba àwọn òṣìṣẹ́ kọsitọọmu kúrò lọ́wọ́ àwọn èèyàn náà, tí wọn sì lewaju wọn kò àwọn ọkọ fayawọ náà dé ọ́fíìsì àwọn kọsitọọmu. 

Akitiyan láti bá alukoro ileeṣẹ VGN nipinlẹ Ogun, Ṣeun Adeboun sọ̀rọ̀ lo ja si pàbó, bẹ́ẹ̀ là kò tíì rí alukoro ileeṣẹ kọsitọọmu, Abdullahi Maiwada náà bá sọ̀rọ̀ tá a fi kọ ìròyìn yìí tán. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI