ẸTANJẸ L'ASAN NI, KO SI ARUN KORONAFAIRỌỌSI NI KOGI - IJỌBA PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, May 31, 2020

ẸTANJẸ L'ASAN NI, KO SI ARUN KORONAFAIRỌỌSI NI KOGI - IJỌBA PARIWO SITA


Ijọba ipinlẹ Kogi ti sọ pe ko si ẹnikẹni to ni arun koronafairọọsi n'ipinlẹ naa, ẹtanjẹ lasan ni.

Kọmiṣanna fọrọ iroyin, Ọgbẹni Kingsley Fanwo lo f'idi ọrọ naa mulẹ laipẹ yii lẹyin ti ajọ to n ri si ọrọ ajakalẹ arun ati aisan lorilẹ-ede yii, NCDC sọ pe awọn ti ri awọn meji to ni arun naa nipinlẹ Kogi.

Kingsley sọ pe ajọ NCDC kan n fi ọrọ arun naa ja orilẹ-ede Naijiria lole lasan ni.

Kọmiṣọnna ọrọ to n lọ ni ipinlẹ ọhun, Kingsley Fanwo lo sọ ọrọ naa ninu iforowerọ pẹlu ileeṣẹ amohunmaworan abẹle Channels.

Fanwo ni "O yẹ ki ajọ NCDC dẹkun ati maa tan awọn eeyan orilẹ-ede yii jẹ pẹlu Coronavirus nitori mi o gbagbọ pe NCDC n ṣe iranlọwọ kankan fun orilẹede yii."

Kọmiṣọnna ọhun tẹsiwaju pe "Ni erongba temi ni pe, afojusun NCDC ni lati pin arun Covid-19 kaakiri orilẹ-ede yii."

Fanwo ṣalaye pe ajọ NCDC fẹ fi tipatikuuku jẹ ki ipinlẹ Kogi ni arun Coronavirus ti ko si yẹ ko ri bẹ.

O ni awọn arun mii wa to n pa awọn eeyan kaakiri Naijiria ju ti Coronavirus lọ bii aisan iba, ṣugbọn Coronavirus ni NCDC joko ti.

Ẹwẹ, adari agba NCDC, Chikwe Ihekweazu ti fesi pe awọn meji kan ti ayẹwo ṣẹṣẹ fihan pe wọn ni arun ọhun sọ pe ipinlẹ Kogi ni wọn ti wa.

Ṣaaju ni NCDC ti sọ pe arun Covid-19 ti rapala wọ ipinlẹ Kogi, ṣugbọn ijọba ipinlẹ naa ni ko si ohun to jọ bẹẹ, eyi si ti n fa họwuhọwu laarin ajọ naa ati ijọba ipinlẹ ọhun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI