ẸṢỌ ÀÀBÒ SO-SAFE BA AGBARIJỌ ẸGBẸ́ ÀWỌN IMAAMU KẸ́DÙN IKÚ ÀÀRẸ ẸGBẸ́ WỌN, OLÓÒGBÉ ỌRUNṢOLU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 26, 2020

ẸṢỌ ÀÀBÒ SO-SAFE BA AGBARIJỌ ẸGBẸ́ ÀWỌN IMAAMU KẸ́DÙN IKÚ ÀÀRẸ ẸGBẸ́ WỌN, OLÓÒGBÉ ỌRUNṢOLU


"Ina Lillahi Wa Ina ilayhi Rajiun" ni ọ̀rọ̀ tí ileeṣẹ eleto ààbò So-Safe Corp nipinlẹ Ogun, èyí tí Kọmanda Sọji Ganzallo je adari wọn fi kẹ́dùn ikú Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn Imaamu àti Aafa nipinlẹ náà, Oloogbe Oloye Sheik Ayinde Liadi Ọrunṣolu to jáde láyé laarọ òní. 

So-Safe ṣàpèjúwe Olóògbé náà gẹ́gẹ́ bí aṣiwaju réré tó ṣeé tọ ipasẹ rẹ, àti pé ipa tó ti ko nínú ẹgbẹ́ náà kò ṣeé fọwọ́ rọ tí sẹ́yìn títí ayé. 

Ninu atẹjade ibanikẹdun tí agbẹnusọ ileeṣẹ So-Safe, Ọgbẹni Mọruf Yusuf fi ranṣẹ sì mọlẹbi, ọrẹ àti agbarijọ ẹgbẹ́ Mùsùlùmí nilẹ Yorùbá, èyí tí ẹda rẹ̀ AWIKONKO lo tí ṣàlàyé pé àdánù ńlá ni ikú Oloye Ọrunṣolu jẹ fún wọn. 

"Ileeṣẹ eleto ààbò So-Safe Corp tí ọga wá Sọji Ganzallo jẹ́ Alakoso rẹ tí bá gbogbo mọlẹbi, ọmọ, ọmọ-ọmọ, ọrẹ, gbogbo agboolé Mùsùlùmí, ẹgbẹ́ àwọn Imaamu àti Aafa nílẹ̀ Yoruba, Ẹdo àti Benin kẹ́dùn ikú ẹni iyì, ẹni ọwọ àti ọjọgbọn tó d'olóògbé. 

Olóògbé, ó Imaamu àgbà ilẹ̀ Ẹ̀gbá, Liadi Ayinde Ọrunṣolu náà jẹ òpó ńlá tó di ileeṣẹ So-Safe mú ṣinṣin nípasẹ̀ àdúrà àti amọran atigbadegba. 

"A gbàdúrà sí Allah wí pé kí ó jẹ ki ẹ jeere iṣẹ yín nípa bí ẹ ṣe ń polongo àlàáfíà lábẹ́ asia ẹsin Isilaamu àti bí ẹ ṣe sìn àwọn èèyàn pẹ̀lú ìtẹríba àti ọkàn ifarajin. 

"Ẹgbẹ́ Mùsùlùmí nilẹ Yorùbá yóò máa ṣàfẹ́rí Baba kan, tí ileeṣẹ So-Safe náà kò ní gbẹ̀yìn láti máa ṣe ìrántí èèyàn Ọlọ́run. 

"A gbàdúrà wí pé kí Allah dárí gbogbo aiṣedeede yín jí yín. Aaaaamin."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI