ẸṢẸ ŃLÁ NÍ TÍ MÍ Ó BÁ LU TYSON FURY - JÓṢÚÀ FARAYA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 6, 2020

ẸṢẸ ŃLÁ NÍ TÍ MÍ Ó BÁ LU TYSON FURY - JÓṢÚÀ FARAYA


Gbajugbaja abẹṣẹkubiojo nnì, Anthony Joshua tí sọ pé ó ṣeé ṣe kí Ọlọ́run má dárí jì òun boun kò bá lu akẹgbẹ òun, Tyson Fury níbi ìjà táwọn jọ ń gbaradi fún.

Joshua, ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lo sọ̀rọ̀ náà laipẹ yìí lásìkò tó ń bá akọroyin DAZN sọ̀rọ̀. Joshua ni òun ti gbaradi dáadáa láti fi ẹnu Fury gbolẹ níwájú gbogbo àgbáyé, tòun yóò sì jẹ kò gbà òun ni ọga pátápátá.

"Mo ti ń ṣiṣẹ gbaradi láti lu Tyson Fury, bóyá àwọn alakọsilẹ {bookmakers}, onigbagbọ tàbí àwọn tó ń ṣiyèméjì fẹẹ wá pẹ̀lú mi tàbí wọn kò fẹ́ ẹ, mo ní láti gbàgbọ́ fúnra mi. Mo ti ń ṣiṣẹ láti lu Tyson Fury. 

Joshua, ọmọ ọgbọn ọdún náà tó ti gba aami ẹyẹ WBA, WBO ati IBF tún sọ pé òun kò fẹẹ rí tí Pulev ro rárá, ṣùgbọ́n tòun tún gbọ́dọ̀ gbé ojú fò ó dà, nítorí pé òun kì í ṣe ẹgbẹ́ rẹ rárá. 

"Ojú tí mo fi ń wo Fury ni pé máa gba ara rẹ kọjá, torí pé máa luu dáadáa, àti pé mi ò fẹ ki àṣìṣe mi lọ́dún tó kọjá tún padà wá, mo fẹ́ tún ń ṣe.

"Ọpọ àwọn èèyàn ní wón kí í mọ nnkan ti àwa tá ń jà ẹsẹ ń lá kọjá nígbà tí wọn ba pàdánù lójú gbogbo ayé, àti nnkan tó máa ń ná wá láti padà wá a jà.

Bákan náà lo sọ pé igbakigba tí Tyson Fury bá ti lòun ṣetan, kò sì ńkan tó ń dá òun dúró láti koju ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI