L'ọjọ Iṣẹgun, Tuside àná ni ẹgbẹ́ àwọn oniṣẹgun òyìnbó, ìyẹn Nigerian Medical Association (NMA), ẹ̀ka t'ipinlẹ Kwara gbé oṣuba káre fún Gómìnà ipinlẹ náà, AbdulRahman AbdulRazaq lórí ìlérí mi-in tó tún mú ṣẹ láti fáwọn eleto Ilera lowo iṣẹ ojúmọ́.
Gómìnà AbdulRazaq lo bù ọwọ luu pé kí gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ eleto ìlera tó bá ń jáde lojoojumọ fun ìpolongo láti dẹkun itankalẹ aarun aṣekupani Covid-19 máa gba owó tí kò dín ni ẹgbẹ̀rún marundinlọgbọn {N25,000} náírà lojoojumọ.
Èyí ni Gomina AbdulRazaq fi ń mọ rírí ipa táwọn òṣìṣẹ́ eleto ìlera ń ko lásìkò tí aarun koronafairọọsi ń bá agbaye, pàápàá Nàìjíríà fínra.
Dọkita Kọlade Ṣọlagberu to jẹ́ alaga ẹgbẹ́ NMA ló ṣiṣọ lójú ọ̀rọ̀ náà wí pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn tí ń rí owó náà gbà báyìí. Dọkita Ṣọlagberu sọ pé owó náà kì í ṣe owó oṣù bí kò ṣe owó ajẹmọnu ojoojumọ t'ijọba ṣèlérí fún wọn.
O ni nnkan iwuri ńlá ni Gomina AbdulRazaq ṣe yìí, tó sì ń yà àwọn lẹ́nu wí pé Gomina mú ìlérí rẹ ṣẹ, tó sì fi ń dá ìjọba lójú wí pé aarun burúkú náà yóò d'ohun ìgbàgbé pátápátá laipẹ.
No comments:
Post a Comment