ÈÈYÀN MÉJÌ KU SÍNÚ ÌJÀMBÁ MỌTO L'ỌTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, May 23, 2020

ÈÈYÀN MÉJÌ KU SÍNÚ ÌJÀMBÁ MỌTO L'ỌTA


Ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu àwọn èèyàn lọsan òní Satide nígbà tí tirela ńlá kan sọ ìjánu rẹ nù lórí ère, tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ èèyàn méjì pá. 

Agbegbe Toll-Gate tó wà ní Sango Ọta nijamba náà tí wáyé ní nǹkan bí aago méjìlá aabọ ọ̀sán. 

Tirela náà ni wọn sọ pé ìlú Èkó lo tí ń bọ̀ kí ìjánu rẹ too ja sọnù, tó sì lọ kọlu mọto kan tí gbé kalẹ sẹgbẹ òpópónà, bẹẹ lo tún forí sọ àwọn mọto mi-ín. 

Asiko ti wọn ni ẹni tó wà tirela ń gbìyànjú láti wá ibi forí sọ lo kọlu àwọn mẹ́ta tí wọn ń kọjá lọ, táwọn méjì sí kú lójú ẹsẹ̀. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI