Pupọ àwọn tó rí gbajumọ oṣere tíátà tó tún jẹ́ onkọrin nii, Angela Okorie níbi to tí ń sunkún pé kí wọn jẹ koun padà silu òun, Nàìjíríà ni wọn ń bàa káàánú, tó sì dabi ẹni pé wọn jii gbé.
Fọ́nrán kan ni arẹwà oṣere tíátà àti onkọrin náà gbé síta laipẹ yìí, tó ń wá ẹkún mú bí egbere wí pé kí wọn jẹ koun padà sílè, ìyẹn Nàìjíríà tòun ti wá.
Ninu fọ́nrán náà tó tẹ AWIKONKO lọ́wọ́ ni ẹni tó ń yà fọ́nrán náà tí ń sọ fún Angela wí pé kò tíì tó asiko ti yoo pada sílè.
Ìlú Johannesburg ni orílẹ̀-èdè South Africa ni obìnrin arẹwà náà wá, tó ti ń sọ̀rọ̀, tí kò sì tíì sẹni tó lè ṣàlàyé nnkan tó gbé e debẹ, pẹ̀lú bí a ṣe gbọ.
Laipẹ yìí làwọn kan fẹ̀sùn kan Angela wí pé ipara ti wọn fi ń bo ara lo ń lo, èyí tí wọn loo hàn nínú ẹsẹ rẹ tó jóná.
No comments:
Post a Comment