Àwọn ọmọ Nàìjíríà tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ kò de láti ìlú Dubai, ìyẹn United Arab Emirate laipẹ ti pariwo síta wi pe afaimọ kò má jẹ́ pé òkú àwọn ọmọ ni wọn yóò padà kò jáde kí òjò mẹ́rìnlá tó o pé.
Lónìí làwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀ jáde wí pé Ìyá ajẹku-dorogbo n'ijọba fi ń jẹ wọn níbi tí wọn kò àwọn pamọ sì, tí wọn kò sì tún fún wọn lounjẹ.
Nínú àwọn èèyàn náà sọ pé àwọn eleto ìlera tí gba ayẹwo lára wọn, tí wọn sì ti fìdí rẹ múlẹ̀ wí pé àwọn kò ní àrùn aṣekupani Covid-19 tí wọn ń pariwo.
Àwọn èèyàn náà làwọn kò lè jáde síta nínú ọgbà otẹẹli tí wọn wá nítorí pé ṣe làwọn ṣọja tí wọn wá nibẹ kò faaye gba wọn láti jáde síta gbatẹgun, tí wọn sì lo ṣeé ṣe kí àìsàn mi-in tún wọlé sí wọn lára.
Síwájú sí ní wọn ní kó sì òṣìṣẹ́ ìjọba kankan tó yọjú sì àwọn látìgbà tí wọn tí wá lahamọ náà, àti pé àwọn òṣìṣẹ́ eleto ìlera NCDC nìkan ló yọjú sì wọn laarọ òní.
No comments:
Post a Comment