Ọjọru, ìyẹn Wẹside àná ni ileeṣẹ tó ń rí s'ọ́rọ epo rọbii {bẹntiroolu} gbé mọto pajawiri fún ìtọ́jú àwọn aláìsàn fún ìjọba ipinlẹ Kwara gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe ń rán àwọn ìjọba lọ́wọ́.
Akọwe Gomina, Rafiu Ajakaye lo fi idi rẹ múlẹ̀ wí pé ìjọba tí tẹwọ gba mọto náà lọ́wọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ileeṣẹ NNPC.
Mọto pajawiri fún itọju náà là gbọ pé tuntun tó bá tigbalode mú ní, tí yóò ṣiṣẹ fún didẹkun itankalẹ àrùn Covid-19.
Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tí wá a fi imọriri hàn, tó sì dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ NNPC fún ẹ̀bùn náà.
Nínú ìròyìn mi-ín tó fara kinra là tí gbọ pé àwọn ileeṣẹ aladani àti àwọn àjọ ẹlẹyinju àánú kọọkan náà ni n'ọwọ iranwọ sì ìjọba lórí ọ̀nà láti tètè dẹkun itankalẹ ajakalẹ àrùn náà.
Lára wọn ni: Oloye Titus Aṣaolu; àjọ Salman Shagaya;agbarijọ ẹgbẹ́ àwọn nọọsi àti eleto ìlera {Professional Association of Public Health Nursing Officers of Nigeria}; Ọgbẹni Owolabi to ni ileeṣẹ Oakleaf Pharmaceutical; ẹgbẹ́ àwọn tó ń sin ẹja, Integrated Fish Farmers Association ni Kwara àtàwọn mi in.
No comments:
Post a Comment