Ìjọba ipinlẹ Kwara lábẹ́ ìṣàkóso Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq tí gbé oriyin rabandẹ-rabandẹ fún àjọ tó kàn tòun náà ń gbógun ti itankalẹ aarun aṣekupani Covid-19, ìyẹn Coalition Against COVID-19, CACOVID lórí àwọn irinṣẹ ìgbàlódé tí wọn fi tà ipinlẹ náà lọrẹ.
Oni tí í ṣe Ọjọru, Wẹside ni àjọ aláàánú náà kò àwọn irinṣẹ ìgbàlódé láti dẹkun itankalẹ aarun aṣekupani Covid-19, ìyẹn koronafairọọsi náà lọ fún ìjọba ipinlẹ Kwara.
Lara àwọn irinṣẹ ìgbàlódé náà ni:
100 bins, stainless steel, ati pedals 8L; 1000 laboratory specimen bottles; 10 oxygen concentrators; 20 oxygen cylinders/regulators; 2500 syringes/needles; five trolleys/ward; 10 chlorine crystals; 1000 goggles; five monitors/patient multiparameters; ati 2500 personal protective equipment (PPEs) — coveralls.
Nígbà tó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àjọ náà, Gómìnà AbdulRazaq sọ pé ìwúrí ńlá ni àwọn ẹ̀bùn tí àjọ náà fi tà ipinlẹ Kwara lọrẹ, to sì ni gbogbo rẹ lo bá ti ìgbàlódé àgbáyé mú.
Rafiu Ajakaye to jẹ́ agbẹnusọ Gómìnà AbdulRazaq lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn nínú atẹjade tó fi ranṣẹ sì AWÍKONKO lo tí sọ pé bí wọn ba gbe ẹṣin kọjá nínú ipinlẹ náà, wọn kò lè kọsẹ, àti pé wọn kò lè sọ bí inú wọn ṣe dùn tó.
Ninu atẹjade náà lo tún ti rawọ ẹ̀bẹ̀ sáwọn ẹlẹyinju àánú, yálà ileeṣẹ àdáni tàbí àwọn olówó láwùjọ láti tọ ipasẹ àjọ CACOVID láti ṣe iranwọ tó bá yẹ fún ìjọba, kí wọn lé dẹkun itankalẹ ajakalẹ aarun kogboogun náà.
Nínú ìròyìn mi-in ni ìjọba yìí tún ti sọ̀rọ̀ lórí ahesọ tó ń káàkiri lórí ayélujára wí pé igbakeji gómìnà, Kayọde Alabi gba ọlọ́pàá kan létí níta gbangba.
Ìjọba ni ìròyìn ẹlẹjẹ pátápátá ní ahesọ náà nítorí pé kò sí nnkan tó jọ bẹẹ rárá. Ó ní erongba àwọn tó ń gbé ahesọ náà káàkiri ní, tí kò sì lè wá simuṣẹ lailai.
O wa a gbà àwọn aráàlú lamọran láti má ṣe gba ìròyìn náà gbọ rárá, nítorí pé ìpolongo ọ̀tẹ̀ fun ìjọba ni wọn ń gbé káàkiri.
Èyí ni esi ayẹwo ajakalẹ aarun COVID-19 tí wọn ṣe lónìí n'ipinlẹ Kwara.
No comments:
Post a Comment