BAALE ILÉ PA ỌMỌ OOJỌ T'IYAWO RẸ BÍ DANU NÍTORÍ TÓ JẸ ỌMỌ-OBÌNRIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 6, 2020

BAALE ILÉ PA ỌMỌ OOJỌ T'IYAWO RẸ BÍ DANU NÍTORÍ TÓ JẸ ỌMỌ-OBÌNRIN


Baálé ilé, ẹni ọdún mọkandinlaadọta kan tí wọn pé orúkọ rẹ ni Ezekiel Anorue lo tí ṣekú pá ọmọ oojọ tí ìyàwó rẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ bí nítorí pé kí í ṣe ọmọbìnrin lo ń retí láti ọ̀dọ̀ ìyàwó rẹ náà. 

Ìyàlẹ́nu ni ọ̀rọ̀ Ezekiel tí wọn ní obìnrin ni gbogbo ọmọ mẹ́rin tí ìyàwó rẹ kọ́kọ́ bí fún un ṣí ń jẹ fún gbogbo èèyàn, pàápàá àwọn ará àgbègbè tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wáyé n'ipinlẹ Imo.

Ezekiel ti wá lahamọ àwọn ọlọ́pàá bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí.

AWÍKONKO gbọ pé ṣe ni ìyàwó Ezekiel ń fi gbogbo ìgbà purọ fún ọkọ rẹ wí pé ọmọkùnrin lo wá nínú òun ni gbogbo asiko tó fi wá nínú oyún.

Wọn ní ìtara wí pé ọmọkùnrin ni Ezekiel ń wá lo fi ń dunkooko mọ ìyàwó rẹ wí pé bí kò bá ti bímọ obìnrin, ó ṣeé ṣe koun leè dànù, ìdí re e tí wọn ní obìnrin náà fi ń purọ wí pé oyún ọkùnrin lo wá nikun òun. 

Nígbà tí obìnrin náà bímọ, tí Ezekiel lọ wo ó ní ọsibitu, ibanujẹ ńlá lo jẹ́ fun-un wí pé ọmọbìnrin níyàwó òun bí, tí mo sì sọ ohunkóhun. 

Bí obìnrin náà ṣe délé, ní wọn loo gbé ọmọ náà silẹ bọ síta, ìgbà tí yóò fi padà wọlé, òkú ọmọ náà lo bá. Lójú ẹsẹ̀ lo tí dimọ ọkọ rẹ lọ́rùn wí pé òun ló pá a. 

Lára àwọn tó gbé ìṣẹ̀lẹ̀ náà sì AWÍKONKO létí jẹ́ kó ye wá pé ṣe ni Ezekiel gbé ọmọ náà níbi tí ìyàwó rẹ gbé e sí, tó sì laa mọ́lẹ̀.

Ezekiel nígbà tó ń sọ̀rọ̀ ni teṣan ọlọ́pàá sọ pé inú lo bí òun wí pé ìyàwó òun purọ foun, ìdí re e tòun fi pá ọmọ náà, bẹẹ lo sọ pé iṣẹ èṣù ni.

Baálè ilé náà sọ pé pẹ̀lú ìdùnnú lòun fi tún gbogbo ilé ṣe, tòun sì ti rà ọ̀pọ̀lọpọ̀ nnkan sínú ilé, lai mọ pe asán lórí asán ni.

Alukoro f'awọn ọlọ́pàá n'ipinlẹ náà tí sọ pé Ezekiel yóò fojú bá ilé-ẹjọ nígbà táwọn bá parí ìwádìí wọn. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI