Ko sẹni to ri bi Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Abiọdun Ige Gani-Adams ṣe n sọrọlaipẹ yii, ti ko ni i mọ pe inu rẹ ko dun rara s'awọn Gomina ilẹ Yoruba, nibi to ti n ṣe olori ogun.
Ọjọbọ, iyẹn Tọside ọsẹ to kọja yii ni Aarẹ Ọna Kakanfo pe aadọta ọdun loke eepe, bo tilẹ jẹ pe eto nla ni wọn ti la kalẹ fun ayẹyẹ naa, ṣugbọn ti aarun aṣekupani kogboogun, iyẹn koronafaiirọọsi ko faaye silẹ lati jẹ ki ayẹyẹ naa wayẹ.
Aarẹ Ọna Kakanfo n'igba to n sọrọ nibi ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ileeṣẹ iwe-iroyin kan lori ikanni Instagram nipa ayẹyẹ ọjọ ibi ẹ. Ninu ọrọ rẹ lo ti sọ pe:
"Eto nla la ti la kalẹ fun ayẹyẹ ọjọ ibi aadọta ọdun yii, nitori pe apẹẹrẹ rere ni. Eniyan lo n rọ, ṣugbọn Ọlọrun lo n fi aṣẹ si i. Ọrọ itankalẹ aarun Covid-19 ti jẹ ka pa ayẹyẹ nla naa ti. Oriṣiriṣi alakalẹ lo ti wa nilẹ fun eto naa. Eyi ti a ṣe yii, emi pẹlu eeyan marun-un pere la ṣe e. A ya fọto, a si jẹun.
"Lati ọmọ ọgbọn ọdun ni mo ti n ṣayẹyẹ ọjọ ibi mi, mi o si ti i pa ọdun kan jẹ ri, ṣugbọn o ṣeni laaanu wi pe Covid-19 ka gba wa laaye lati ṣe ayẹyẹ t'ọdun yii.
"Inu iyẹwu mi ni mo wa nigba to ku wakati kan gbako ki aagp mejila ọjọ ayẹyẹ ọjọ ibi mi lu. Mo n kọrin idupẹ si Ọlọrun, bẹẹ ni mo n gbadura. Bi aago mejila ṣe lu ni mo ti n ri atẹjiṣẹ gba lati ọdọ awọn eeyan kaakiri, t'awọn kan si n pe mi ki.
"Ko le ya yin lẹnu wi pe ko si Gomina ilẹ Yoruba kankan to fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si mi lati ki mi, wọn ko ki mi sinu awọn iwe iroyin kankan, ṣe ẹyin naa ri i. Iru eso wo la n gbin fun ara wa niẹ Yoruba yii.
"Nigba ti ogun ba si de, gbogbo awọn eeyan yii lẹ maa ri, ti wọn ma maa bu mi kaakiri. Awọn lẹ maa ri ti wọn ma maa sọ pe ki ni ipa ti Aarẹ n ko, ati pe ki ni ojuṣe Arẹ Ọna Kakanfo. Wọn ti gbagbe wi pe Aarẹ ko gba owo oṣu bi awọn Ọba.
"Ẹ jẹ ki Gomina kan jade sita lati wa a sọ pe oun gbe iṣẹ akanṣe fun mi lati ṣe, ko da, awọn araalu ti wọn tu n bu ẹnu atẹ lu wa, ko si eyi to gbe iṣẹ fun mi. Ṣugbọn bi eeyan ba ti jẹ iranṣẹ Ọlọrun, Ọlọrun naa ni yoo ti i lẹyin. Ọlọrun yoo yanju iṣoro aa lẹsẹẹsẹ.
"Ko digba ti o ba n wa iranlọwọ ẹda ki o to o ṣe oriire laye. Itiju nla lo yẹ ko jẹ fun pupọ ninu wọn wi pe ẹni ti n pe ni jagunjagun n ṣayẹyẹ ọjọ ibi aadọta ọdun, wọn ko si le ri nnkan ṣe si i. A ko le kọ lẹta si wọn nitori Covid-19, ṣugbọn sibẹ, wọn n ri ipolongo to ti n lọ kaakiri lori awọn iwe iroyin ati lori ayelujara, wọn ko le sọ pe awọn ko ri i.
"Awọn agba Yoruba kan pe mi. O yẹ ki eto wa fun iru awa eeyan pataki bayii lasiko to ba yẹ. Sibẹ-sibẹ, iyẹn ko le di mi lọwọ nitori pe mo ni oore-ọfẹ to n jẹ ki n maa tẹsiwaju.
No comments:
Post a Comment