Gbogbo àwọn ọmọ ipinlẹ Kwara káàkiri àgbáyé ni wọn ti ń gbé oṣuba rabandẹ-rabandẹ fún Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ náà lórí àwọn àkànṣe iṣẹ alaragbayida tó ti ń ṣe láti bí ọdún kan to gba ipò.
Kii ṣe ahesọ, tàbí asọdun wí pé bí wọn ba n ka àwọn ipinlẹ tí ọwọ aago wọn tí jọ ajorẹyin lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́dún kan sẹ́yìn, ọkàn pàtàkì ni ipinlẹ Kwara jẹ nínú wọn. Ohun gbogbo lo dórí kodò, igbe tani yóò gbà wá làwọn ọmọ àti olùgbé ipinlẹ náà ń ké káàkiri.
Ṣùgbọ́n látìgbà tí AbdulRahman AbdulRazaq tí gba ipò Gómìnà, tó sì búra níwájú àwọn ọmọ àti olùgbé ìlú náà káàkiri àgbáyé lọ́jọ́ kọkandinlọgbọn oṣù karùn-ún ọdún tó kọjá làwọn èèyàn ti ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ẹlẹ́dàá wọn wí pé àtẹ̀gùn àlàáfíà tí ń fẹ́ lu wọn.
Kí olójú too ṣẹ ẹ, àwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sii rí àyípadà rere, wọn si ti ń kọrin ọpẹ wí pé Ọlọ́run ti rán Mèsáyà {Messiah} tí yóò gbà wọn silẹ sì wọn. Omi tuntun ru, ẹja gidi ń sọ nisalẹ odò. Àwọn èèyàn ń gbé oṣuba àti sadankata fún Gomina AbdulRazaq.
Laarọ òní ni akọwe Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye fi atẹjade kan ranṣẹ sì AWIKONKO, níbi to tí mẹnuba àwọn ipa ribiribi tí Gomina alaragbayida AbdulRazaq tí kò nipinlẹ náà laarin ọdún kan. Ó ní kii se pe AbdulRazaq jẹ àǹfààní ńlá fún ipinlẹ náà, ó loo tún jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti Olùgbàlà táwọn èèyàn ti ń retí lọ́jọ́ tó ti pẹ.
Díẹ̀ re e lára ọ̀rọ̀ tí Rafiu Ajakaye kọ nípa Gómìnà asọludẹrọ:
"Ni wákàtí díẹ̀ sì asiko taa wá yìí, gbogbo àwọn ìwé ìròyìn pátápátá jákèjádò ni yóò kún fún oriyin lórí iṣẹ gbogbo àwọn adarí pátápátá lórílẹ-èdè Nàìjíríà. Òtítọ́ ni èyí jẹ́, pàápàá fún gbogbo àwọn tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ de ipo Gómìnà, tí wọn sì búra fún lọ́jọ́ kọkandinlọgbọn, oṣù karùn-ún ọdún 2019. Ìpínlẹ̀ Kwara kò yàtọ̀ rara. Àwọn ọrẹ, ojulumọ ìjọba AbdulRahman AbdulRazaq, pàápàá àwọn wọn tí ń gbé oṣuba káre fún un, nítorí pé ó ti ṣí iyè ọpọ àwọn èèyàn sì idagbasoke.
"Agbegbe kan tó ṣajoji ni Kwara jẹ. Oṣù méjìlá sẹ́yìn tí mú ìdùnnú àti ayọ wá. Bí ẹ bá wo àwọn nǹkan tó wà nilẹ, kò sì ẹni tí orí ẹ pé tí yóò sọ pé ìṣàkóso AbdulRazaq kò tíì ṣiṣẹ kọjá ìdá àádọ́rin {70%}, pẹ̀lú bo ṣe jẹ́ pé gbogbo ẹka pátápátá lo tí fọwọ́ kan. Àwọn ẹ̀ka bii: Ètò Ẹ̀kọ́, Ìlera Aráàlú, Àwọn ọdọ àti eré ìdárayá, iṣẹ àgbẹ̀, omi, òpópónà tí wọn tí na owo ńlá lè lórí.
Ajakaye tẹsiwaju pé àwọn àkànṣe iṣẹ ńlá-ńlá tí Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq ń ṣe yìí, tí jẹ́ kí ìrònú pupọ àwọn èèyàn yí padà, tí wọn sì ti fún un lórúkọ 'àdììtú'.
"Ko sẹni tó lè ṣàpèjúwe àdììtú, ṣùgbọ́n ó lè tún ilé tó, bẹẹ lo tún lè tú ìlú ká'"
Ó tún sọ pé fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, inú ibẹrubojo làwọn èèyàn agbegbe Ahmadu Bello ń gbé. Àwọn alágbára ń fìyà jẹ àwọn èèyàn, wọn si n gbe igbe ayé familete-ki-n-tutọ. Wọn ń jẹ gàba lè àwọn mẹkunnu lórí lọ́nà àìtọ́. Àwọn èèyàn yìí ń jaye bo ṣe wù wọn nínú àwọn nǹkan perete tó wà nílẹ̀, wọn kò ṣiṣẹ kankan siluu fáwọn aráàlú, wọn kò sì là ojú àwọn èèyàn sì idagbasoke.
Àṣírí tí tú, ojú tí la
"Kii ṣe pé AbdulRazaq náà pé laarin oṣù méjìlá sì asiko yii, ṣùgbọ́n ìyàtọ̀ tí farahàn gedegbe láàárín kijipa àti aṣọ. AbdulRazaq tí là ojú àwọn èèyàn sì ohun tí ipò Gomina jẹ́, òye àwọn èèyàn sì ti ṣí - wí pé àwọn tó ń di ipo yìí mú là yàn síbẹ̀ láti di ipo agbára mú, kí wọn sì lè ṣe ìfẹ́ àwọn aráàlú, tí wọn sì láṣẹ láti béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wọn nípa iṣẹ tí wọn ń ṣe, àti pàápàá lórí ọ̀rọ̀ aráàlú.
"Ọpọ ìgbà ni Gómìnà tí lọ káàkiri, tó sì ti dúró láti báwọn èèyàn ṣeré, tí wọn tún jọ yà fọto, ìyẹn àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sii. Fúnra rẹ lo ń gbé baagi rẹ. Fúnra rẹ lo ń gbé àwọn ìwé rẹ dání. Pupọ ìgbà lo tí ń ṣáájú àwọn tó bá pèé sì òde debẹ, pàápàá lásìkò tí wọn kò bá tíì ṣetan láti bere eto wọn. Orí ìdúró lo máa ń wà láti báwọn èèyàn sọ̀rọ̀. To bá pẹ de ìpàdé tàbí òde kan, ṣe ni yóò rọra wọlé lai je kẹnikẹni mọ.
Ajakaye ni èyí kò wọ́pọ̀ láàárín àwọn adari wá nítorí pé bí pupọ wọn ba pẹ de ìpàdé tàbí ayẹyẹ kan, ṣe ni wọn yóò tún gbé ariwo debẹ, táwọn ẹṣọ ààbò wọn yóò tún máa lé àwọn èèyàn dànù fún wọn, èyí tó ní kó rí bẹ́ẹ̀ lọdọ AbdulRazaq. Ó ní gbogbo èyí ni Gomina AbdulRazaq tí yí padà pátápátá nípa bó ṣe ń lá ojú àwọn èèyàn sì ohun tí ìṣàkóso àti ìjọba jẹ́.
Ó ní ohun tó ti ń jẹ ìrètí pupọ àwọn èèyàn ní pe ni kété tí wọn búra fún Gómìnà AbdulRazaq làwọn kan tí ń fojú sọ́nà wí pé yóò lè àwọn àgbààgbà kan kúrò nìdí iṣẹ ìjọba nítorí pé wọn tí ṣíṣẹ fún ìjọba tó kọjá.
Akọwe Gómìnà ni ẹgbẹ̀rún méjì àwọn olùkọ́ tijọba àná lo ni wọn ń retí idaduro lẹ́nu ìṣẹ. Àwọn èèyàn ń fẹ́ kí ìṣàkóso yìí lè àwọn alágbára kúrò n'ilu, nítorí bí wọn ṣe gbabọdi, wọn si n fẹ́ kí wọn fi ìtìjú lè wọn dànù, ṣùgbọ́n tí ìjọba yìí kò rí bẹ́ẹ̀.
"Àwọn èèyàn fẹ ki oríṣiríṣi ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ìṣàkóso yìí. Wọn ń fẹ́ káwọn nnkan tó ti ṣẹlẹ̀ nijọba tó kọjá lọ ṣì máa tẹsiwaju. Eyi tó ń ṣe kàyéfì nibẹ ni pé àwọn ìwà tó mú káwọn èèyàn dìde lòdì sí ìṣàkóso tó kọjá ní wọn ń fẹ́ kí ìjọba yìí tẹsiwaju wọn. Kí ló dé tí wọn ń fẹ́ káwọn nnkan yìí tún ṣí máa lọ bẹ́ẹ̀ nínú ìṣàkóso àyípadà? Ìdí ni pé ohun tó ti mọ pupọ àwọn èèyàn lára ni. Àwọn ìwà burúkú tí kò yẹ ọmọlúwàbí yìí ló ti di ìṣe. Àwọn ìwà burúkú yìí tí jingiri mọ àwọn èèyàn lára, kò sì yẹ kó rí bẹ́ẹ̀. Eyii tí fi hàn irú ìwà ibajẹ tí ìjọba tí wọn lé dànù tí gbìn sínú ayé àwọn èèyàn.
"Wí pé Gómìnà AbdulRazaq kò tọ́ ipasẹ ìjọba tó kọjá lọ tún ń jẹ àdììtú lọ́tọ̀. Àwọn ìwà tuntun yìí sí ti ń bá àwọn èèyàn lára mu.
Ó ní fún ìgbà àkọ́kọ́ láti bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, ìjọba yìí tí ń jẹ káwọn aráàlú máa mọ bí owó wọn ṣe ń rìn-ín. Tó sì fi ń dá wọn lójú pé aagun ojú wọn, ìyẹn owó orí wọn kò lọ lofo.
"Ìjọba yìí tí pín àwọn nǹkan bíi oúnjẹ àti igbayegbadun {palliatives} tí owó ẹ lè ní ẹẹdẹgbẹta miliọnu {N500m} náírà lásìkò konilegbele tí ajakalẹ àrùn COVID-19. Ìpinnu Gomina ni pé kí gbogbo àwọn nǹkan tí wọn pín náà lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ju díẹ̀ kaato fún, pàápàá àwọn aláìní láwùjọ káàkiri ipinlẹ náà.
"Pẹ̀lú iranlọwọ igbakeji rẹ, Ọgbẹni Kayọde Alabi, nipasẹ ìbúra tí wọn bù fáwọn aráàlú wí pé àwọn kò níí ṣe ojúsàájú ni wọn ti sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ fi ẹlẹyamẹya tàbí òṣèlú pín àwọn nǹkan náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan tako èyí, ṣùgbọ́n Gomina dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ wí pé boun ṣe fẹẹ nìyẹn, nítorí pé gbogbo èèyàn ni wọn gbọ́dọ̀ gbádùn nínú ìjọba òun. Èyí kii se Kwara tí gbogbo wa mo!
Ó ní bí ìjọba yìí ṣe ń ṣayẹyẹ ọdún kan lórí ipò, ọkàn lára àwọn ìlànà rere tó fẹẹ fi silẹ ni bo se parí gbogbo àwọn àkànṣe iṣẹ́ tó jogún bá lọ́wọ́ ìṣàkóso tó kọjá.
"Ní tiẹ̀, owó orí àwọn aráàlú ni wọn fi bẹ̀rẹ̀ àwọn àkànṣe iṣẹ́ náà, oogun ojú aráàlú kò sì gbọ́dọ̀ lọ lásán. Wọn kò gbọ́dọ̀ fi òṣèlú tàbí ẹtanu dalẹ aráàlú. Pupọ àwọn àkànṣe iṣẹ aṣepati lo ṣí wá káàkiri ipinlẹ náà, nítorí pé òṣèlú ẹtanu lo jẹ́ káwọn ìjọba tó re kọjá pá wọn tí.
Fún ìgbà àkọ́kọ́ nílẹ̀ adulawọ, Ajakaye sọ pé ìjọba ipinlẹ náà lo yàn obìnrin pupọ sínú ìjọba rẹ, t'awọn obìnrin náà sì lè díẹ̀ ni ida-àádọ́ta {56.25%}.
"Ní Kwara lónìí, àwọn èèyàn kò nílò ipò òṣèlú láti gba nnkan ti wọn n fẹ́ lọ́wọ́ ìjọba. Ìyẹn yà yín lẹ́nu? Ẹ lọ béèrè lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọn ń jẹ àǹfààní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ lọ́wọ́. Ẹ béèrè lowo àwọn awakọ tí wọn jẹ àǹfààní owó iranwọ, ẹ béèrè lọ́wọ́ àwọn arúgbó. Kò sẹni tó béèrè káàdì ẹgbẹ́ lọ́wọ́ wọn tàbí inú ẹgbẹ́ òṣèlú tí wọn wá kì wọn tó jẹ́ àǹfààní yìí. Èyí kii ṣe Kwara tí a mọ tẹ́lẹ̀.
Ó tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ wí pé "
Gomina tí ṣe kọjá afẹnuroyin nípa ìdàgbàsókè, pàápàá julọ nípa ríran àwọn aláìní lọ́wọ́. Kwara tí wá a ní àwọn ọsibitu tó kún ojú òṣùwọ̀n pelu awon irinṣẹ ìgbàlódé. Àwọn iléèwé tí wá nípò tó yẹ kí wọn wá. Omi tí ń yọ káàkiri àwọn ìlú. Pupọ àwọn àgbègbè àti àdúgbò ni òpópónà tó já geere tí gba kọjá.
No comments:
Post a Comment