AYÉ MA N'IKA O! GÓMÌNÀ WIKE TÚN GBÉ ÌWÀ OLÓṢÈLÚ DÌDE LÁSÌKÒ KÓNÍLÉGBÉLÉ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, May 13, 2020

AYÉ MA N'IKA O! GÓMÌNÀ WIKE TÚN GBÉ ÌWÀ OLÓṢÈLÚ DÌDE LÁSÌKÒ KÓNÍLÉGBÉLÉ


Ko sẹni to gbọ ọ̀rọ̀ náà lónìí, tí kò yà lẹ́nu, kódà tí ọ̀rọ̀ náà tí di àkòrí ọ̀rọ̀ káàkiri ileeṣẹ rédíò, ìwé-ìròyìn tó fi mọ àwùjọ, lórí bí Gómìnà ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ṣe lòun yóò fi ibi tí wón ti wo otẹẹli kan kọ ilé-ẹ̀kọ́ alakọbẹrẹ fáwọn aráàlú.

Bẹ ó bá gbàgbé, laipẹ yìí ni Gómìnà Wike pàṣẹ wí pé kí wọn lọọ wo àwọn otẹẹli méjì kan, ìyẹn Prodest tó wà n'ijọba ìbílẹ̀ Ẹlẹmẹ lórí ẹ̀sùn tó fi kan wọn wí pé wọ́n tàpá sì òfin konile-o-gbele àti ipẹjọpọ èèyàn rẹpẹtẹ. 

A gbọ pé wàhálà ńlá ṣẹlẹ̀ lásìkò tí wọn fẹẹ wo otẹẹli Prodest, níbi tí wọn ní wọn tí lu ọkàn lára àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó lọ síbẹ̀, tí wọn sì lẹni náà padà kú. 

Lónìí ní Kọmiṣanna f'eto ìròyìn àti ikansira-ẹni, Paulinus Nsirim báwọn oniroyin sọ̀rọ̀, tó sì fi yẹ wọn pé ilé-ẹ̀kọ́ náà yóò wúlò pupọ fáwọn tó ń gbé lágbègbè yìí.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI