ÀWỌN AGBABỌỌLU MẸ́JỌ TÚN LUGBADI ÀRÙN KORONAFAIRỌỌSI NI MEXICO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, May 21, 2020

ÀWỌN AGBABỌỌLU MẸ́JỌ TÚN LUGBADI ÀRÙN KORONAFAIRỌỌSI NI MEXICO


Àwọn aláṣẹ ère bọọlu lórílẹ̀-èdè Mexico tí kéde síta wí pé àwọn agbabọọlu mẹ́jọ lo tí lugbadi àrùn aṣekupani, Covid-19 lèyí tí yóò dènà idije tó fẹẹ bẹ̀rẹ̀ padà lẹ́yìn oṣù méjì. 

Àwọn agbabọọlu tínu ẹgbẹ́ Santos Laguna ni wọn kéde síta lọ́jọ́ Wẹside àná wí pé yóò di wọn lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ idije tí wọn pati tipẹ náà padà.

Òpin ọ̀sẹ̀ yìí là gbọ pé idije tó ń wáyé lórílẹ̀-èdè náà, ìyẹn Liga MX yóò bẹ̀rẹ̀ ni pẹrẹu, ìdí rẹ tí wọn ṣe ń ṣàyẹ̀wò fún gbogbo àwọn agbabọọlu tí yóò kopa, tí àyẹ̀wò sì fìdí rẹ múlẹ̀ wí pé àwọn mẹjọ ni wọn ti kagbako àrùn náà. 

Aláṣẹ Santos Laguna, Alejandro Irarragorri, sọ pé àwọn kò tíì lè sọ pàtó bóyá idije náà yóò bẹ̀rẹ̀ padà, tàbí káwọn ṣí wọgi lee. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI