Àná tí í ṣe ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù kẹrin lo pé ọdún mẹtadinlogun tí Gbenga Abẹfẹ Adeboye dagbere fáyé, tó sì jẹ pupọ àwọn sọrọsọrọ káàkiri àgbáyé, pàápàá lórílẹ̀-ède Nàìjíríà ni wọn ń ṣe ìrántí títí di àsìkò yìí.
Lasiko táwọn èèyàn ń sọ oríṣiríṣi nípa ìwà Olóògbé Gbenga Adeboye tí wọn tún ń pè ní Jengbetiele nígbà ayé rẹ, pàápàá ipa tó kọ láyé àwọn èèyàn ni ọkàn pàtàkì lára àwọn sọrọsọrọ n'ipinlẹ Ogun, Olumide Awolọwọ tí sọ pé kò sí nnkan tó lè mú koun gbàgbé olóògbé náà.
Awolọwọ táwọn èèyàn ń pè ní Ọrọbọ Pirisẹnta {Presenter} tẹle, ṣùgbọ́n tí wọn tún ti ń pe e ni Gẹdú Masita {Master} báyìí sọ pé lára àwọn àdúrà àti àsọtẹ́lẹ̀ Gbenga Adeboye nínú ayé òun ló ń gbé òun borí ogun títí di àsìkò yìí.
Orí ìkànnì ayélujára tí ibara-ẹni-sọrọ, ìyẹn wasaapu lo tí sọ̀rọ̀ náà ni ọsan àná nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àpilẹ̀kọ tí Ààrẹ Ẹgbẹ́ sọrọsọrọ, Kọmureedi Desmond Nwachukwu kọ nípa Adeboye.
Awolọwọ ni "Èmi gẹ́gẹ́ bí ẹnikan, mi ò lè gbàgbé Gbenga Adeboye lọnakọna. Mo l'anfaani láti sọ̀rọ̀ lórí redio fún ìgbà àkọ́kọ́ lórí eto Gbenga Adeboye nileeṣẹ redio OGBC.
"Ẹẹkeji ni pé, Gbenga Adeboye sọ àsọtẹ́lẹ̀ tó mú kí n bí ọmọ mi obìnrin lọ́jọ́ tí Adeboye dagbere fàyè.
"Gbenga Adeboye tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ wí pé àwọn kan nínú àwọn sọrọsọrọ ẹgbẹ́ wá yóò dìde lòdì sí mi lori àwọn nǹkan tòun ń sọ nípa mi, ó sì dárúkọ àwọn méjì. Ẹni kínní nínú àwọn méjèèjì yìí ló rán àwọn agbanipa sì mi lọ́dún 2011, ṣùgbọ́n tí orí kò mi yọ.
"Báwo ni máa ṣe gbàgbé Ọmọba Gbenga Adeboye tó ti papoda. Igbe ayé tó ṣe é mú yangàn ni Olóògbé yìí gbé, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run wí pé aami to fi sì mi lára ṣí wá nibẹ."
Bákan náà ni Awolọwọ tún fi asiko náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àkọ́bí rẹ tó jẹ́ obìnrin, tó jẹ́ àná yìí náà ni ayẹyẹ ọjọ́ ẹ bọ sì.
No comments:
Post a Comment