Àjọ eleto ìlera lagbaye, World Health Organisation {WHO} tí pariwo síta wí pé ó ṣeé ṣe kí aarun aṣekupani tó ń fi gbogbo agbaye lakalaka lásìkò yìí, ìyẹn Koronafairọọsi tí wọn tún ń pè ní COVID-19 má kasẹ kúrò nílẹ̀ rárá.
Ohun tí a gbọ pé ó fà á ọ̀rọ̀ yìí ni bí wọn ṣe làwọn kan ń sọ̀rọ̀ lórí ọjọ́ tí aarun náà yóò dópin itankalẹ, tí wọn sì ń bẹbẹ fún ifọwọsowọpọ àwọn èèyàn láti gbógun tíì.
Ọkàn lára àwọn ọga àgbà l'ẹka ìṣẹ̀lẹ̀ pajawiri, Mike Ryan lo sọrọ náà síta lọjọ Wẹside tó kọjá yìí. Ó ní o ṣé pàtàkì fáwọn èèyàn láti mọ wí pé ajakalẹ àrùn yìí tún lè gbà ọ̀nà mi-in yọ káàkiri agbegbe wá.
"Ó ṣe pàtàkì wí pé ní láti sọ òtítọ́ fún ara wa, mi o sì lérò wí pé ó yẹ ká máa fi ojú woye ìgbà tàbí àkókò tí àrùn yìí yóò pòórá. Mo lérò wí pé kò sí ìlérí kankan nìdí ẹ, kò sì ní àsìkò. Àrùn yìí tún lè kọjá ojú tí a fi ń wo ó, kò sì tún di wàhálà ọlọ́jọ́ pipẹ tàbí kó má rí bẹ́ẹ̀.
No comments:
Post a Comment