Aarẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Muhammadu Buhari tí ṣàpèjúwe màmá Gómìnà ipinlẹ Kwara, Alaaja Raliat Amọpe AbdulRazaq to ń ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí àádọ́rùn-ún ọdún rẹ lókè eepẹ gẹ́gẹ́ bí abiyamọ tó ń dúró tini lọ́jọ́ ìṣòro.
Ọjọ́ Ajé, ìyẹn Mọnde àná ni Ààrẹ Buhari sọ̀rọ̀ yìí nínú atẹjade tó fi ranṣẹ sì Gómìnà AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara àti bàbà rẹ, Alaaji A. G. F. AbdulRazaq to je agbẹjọro àkọ́kọ́ nílẹ̀ Hausa fún tí ayẹyẹ náà.
Alaaja Raliat Amọpe ni oludasilẹ àjọ aláàánú Raliat Foundation, tó sì ti tipasẹ àjọ náà ṣe iranlọwọ fún akaakatan àwọn èèyàn, pàápàá àwọn tó wà nínú ìṣòro.
Òní ni ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Alaaja Raliat Amọpe AbdulRazaq, táwọn èèyàn káàkiri àgbáyé sì ti ń fi atẹjiṣẹ oríṣiríṣi ranṣẹ sii láti bàa ṣajọyọ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí náà.
Ààrẹ Buhari gbàdúrà ẹmi gígùn àti àlàáfíà fún Alaaja Amọpe.
No comments:
Post a Comment