Minisita eto ilera ni Naijiria, Dokita Osagie Ehanire sọ pe ijọba yoo ṣe iwadii ohun to faa gan an ti ipinlẹ Kogi ati Cross River ko fi tii ni akọsilẹ aarun coronavirus.
Dokita Osagie ṣalaye awọn eeyan ti ijọba kọkọ ran lọ si ipinlẹ Kogi kuna nitori ede-ai-yede to ṣẹlẹ laarun awọn eeyan naa ati ijọba ipinlẹ Kogi.
Minisita ni igbesẹ ti ijọba yoo gbe naa ni lati ṣabẹwo si awọn ipinlẹ pada.
Dokita Osagie ni ọsẹ ti o n bọ yii naa ni ijọba yoo ran awọn si ipinlẹ Cross River ati Kogi lati ṣiṣẹ iwadii naa.
Atupalẹ awọn ipinlẹ to ni coronavirus ni Naijiria
Titi di ọjọ kejila osu kini ọdun 2020,orileede China nikan ni o ni eeyan to ni arun coronavirus.
Ṣugbọn nigba ti yoo fi di ọjọ kẹtala, kokoro aifojuri yi di ajakalẹ ti awọn orilẹede bi Thailand, Japan, South Korea ati Amẹrika naa si bẹrẹ si ni kede awọn to kọkọ nii lọdọ wọn.
Laipẹ, arun yi tan kaakiri de agbaye, koda ilẹ Afrika naa ba wọn nipin ninu rẹ.
O le ni miliọnu mẹta eeyan to ti ni Coronavirus lagbaye gẹgẹ bi iroyin to n jade lọdọ ileeṣẹ to n pese iroyin nipa Coronavirus ti fasiti John Hopkins l'Amẹrika.
Ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keji ni Naijiria kede ẹni akọkọ ti yoo ni arun yii lẹyin ti arakunrin ọmọ orileede Italy kan gbe wọle ti ayẹwo si fihan pe o ni Covid-19.
Lọjọ kẹsan osu kẹta, Naijiria kede ẹni keji iyẹn ọmọ Naijiria to ṣalabapade ọmọ Italy to gbe arun naa wọle.
Lẹhin naa, awọn to ni arun naa bẹrẹ si ni pọ si.
Iroyin to n tẹwa lọwọ lati ileesẹ to n gbogun ti idena aisan ni Naijira, NCDC, wọn ni eeyan 3,912 lawọn ti fidi rẹ mulẹ pe wọn ni arun yi,ti ilu Eko si ni iye awọn to pọju tii se 1,667.
Awọn to ti ba Coronavirus lọ ti wọ mẹtadinlọgọfa ti awọn ti ara wọn ya lẹyin itọju si jẹ 679.
Ipinlẹ mẹrinlelogoji pẹlu olu ilu Naijiria, Abuja ni coronavirus ti wọ pẹlu ohun ti a ri gbọ lọdọ wọn lọwọ yi.
Ni bayii, ipinlẹ Kogi ati Cross River ni ipinlẹ meji ti aarun covid-19 ko tii wọ lorilẹede Naijiria.
ATUPALE BI NNKAN SE RI PELU CORONAVIRUS NI NAIJIRIA TITI DI ỌJỌ́ KEFA OSU KAARUN 2020
Iye ayẹwo ti wọn ti se - 23,835
Iye awọn to ni arun naa ti wọn fidi rẹ mulẹ- 3,912
Awọn tara wọn ya - 679.
Awọn to gba tọwọ rẹ ku - 117
Ìpínlẹ̀ | Iye awọn to laarun Covid-19 | Awọn to wa nibudo iyasọtọ | Awọn to ti gbadun | Awọn to ti ku
Lagos 1,667 1,186 448 33
Abuja FCT 336 292 40 4
Kano 547 509 20 18
Gombe 110 100 10 0
Borno 142 128 0 14
Ogun 113 81 28 4
Katsina 137 120 9 8
Edo 67 51 12 4
Osun 38 4 30 4
Kaduna 95 79 14 2
Bauchi 117 110 6 1
Sokoto 93 80 4 9
Oyo 59 43 14 2
Akwa Ibom 17 5 10 2
Kwara 24 15 9 0
Ekiti 12 7 4 1
Ondo 15 9 6 0
Taraba 15 15 0 0
Delta 17 11 3 3
Rivers 21 15 4 2
Jigawa 83 82 0 1
Benue 2 2 0 0
Anambra 1 0 1 0
Zamfara 65 62 0 3
Abia 2 1 1 0
Enugu 10 8 2 0
Niger 6 4 2 0
Adamawa 15 15 0 0
Plateau 15 14 1 0
Imo 3 2 1 0
Bayelsa 5 5 0 0
Ebonyi 7 7 0 0
Kebbi 18 18 0 0
Nasarawa 25 24 0 1
Yobe 13 12 0 1
Bi Coronavirus se n tan kiri Naijiria ti awọn orileede agbaye miranon mii si n ka iye awọn to gba tọwọ rẹ ku to fi mọ awọn miran to n ko lojumọ,ipinlẹ meji kan ni Naijiria wa ti ko ti d'ọdọ wọn.
•Ipinlẹ Cross Rivers
•Ipinlẹ Kogi
Lati igba ti Covid-19 ti bẹrẹ ni Naijria awọn ipinlẹ mejeeji wọn yi gbe awọn igbesẹ kan lati ma se jẹ ki o wọ ọdọ wọn ti wọn si ti n gbaradi de bi o ba fi le wọ ọdọ wọn.
Ijọba Cross River lawọn ti mura de tawọn si ti se ibomu to pọ pẹlu pe wọn pọn dandan lilo rẹ fara ilu.
Gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello sọ pe awọn ti se appu kan eleyi ti yoo jẹ ki awọn mọ apẹrẹ arun naa.
Láti: BBC
No comments:
Post a Comment