YEEPA! AGBABỌỌLU ỌGBỌN F'OJU BA ILE ẸJỌ NI KANO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, April 23, 2020

YEEPA! AGBABỌỌLU ỌGBỌN F'OJU BA ILE ẸJỌ NI KANO

Awọn agbabọọlu ti ko din ni ọgbọn ni wọn ti f'ọju ba ile ẹjọ n'ipinlẹ Kano bayii, lori bi wọn ṣe tapa si ofin konilegbele to n lọlọwọ kaakiri agbaye lasiko yii.

Ọjọ kẹrinla oṣu ti a wa yii níjọba ipinlẹ Kano labẹ Gomina Abdullahi Ganduje paṣẹ wi pe ki gbogbo awọn araalu jokoo sile wọn bẹrẹ lati ọjọ kẹrindinlogun, ati pe wọn ko gbọdọ jade lọ sibikibi fun ọjọ meje gbako.
Si iyalẹnu l'ọjọ Mọnde ana l'awọn gendekunrin n'ijọba ibilẹ Dala, ipinlẹ naa ko ara wọn jọ lati gba bọọlu fun idaraya, eyi to si tako ofin ati ilana aṣẹ ijọba.

Lara awọn to ri wọn nibi ti wọn ti n gba bọọlu naa lo ta awọn agbofinro leti, ti wọn fi lọ ko wọn.
Nigba to n sọrọ, agbẹnusọ awọn ọlọpaa nipinlẹ naa, DSP Abdullahi Haruna sọ pe gbogbo awọn eeyan naa ni yoo foju winna ofin nitori pe ilu ti ko si ofin, ẹṣẹ ko si nibẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI