Àwọn aláṣẹ l'ẹka eto iṣẹ agbẹ àti ọ̀gbìn nilẹ Amẹ́ríkà tí sọ pé ayẹwo kan tí wọn ṣe lára ohun ọ̀sìn nnì, Amọtẹkun tí wọn ń pè ní Tiger tí fìdí rẹ múlẹ̀ wí pé ẹranko náà ni aarun àṣekupani tí Coronavirus tó ń jà káàkiri àgbáyé.
Amọtẹkun náà tí wọn ní ọgbà àwọn ẹranko tí Bronx Zoo tó wà n'ilu New York lo wa ni wọn ti sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn aṣọgba lo kò aaru náà rán Amọtẹkun yìí.
Amọtẹkun náà tí wọn fún lórúkọ Nadia là gbọ pé oríṣiríṣi àwọn èèyàn ló ti ń wo láti ọjọ́ kẹrindinlogun oṣù tó kọjá. Lójijì ni wọn lo ó dubulẹ àìsàn, tí wọn sì ṣàyẹ̀wò Koronafairọs fún tí, ayẹwo náà lo fi ye wọn pé aarun náà wá lára rẹ gidigidi.
No comments:
Post a Comment