Ṣáájú ni o ti gbé e sí orí àtẹ̀jísẹ́ instagram rẹ̀ pé "ọmọ ọlọ́jọ́ ìbí, Jésù mo dúpẹ́ fún ìfẹ́ rẹ̀. Mi ò ní ya aláìmoore."
Gbajúmò óṣeré tíátà lóbìnrin, Toyin Abraham tí kéde pé, ilé ọkọ tí òun wa ti mú àyípadà rere bá igbe ayé òun.
Toyin, lásìkò to ń sọ̀rọ̀ lórí eto orí telifisan kan n'ilu Eko ṣàlàyé pé, ọkọ òun, tíì ṣe ẹni tó lọgbọn nínú ìwà àti ọpọlọ, tí mú àyípadà réré bá igbe ayé òun, yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀.
Toyin ni "Ìrírí tuntun ni ìgbéyàwó jẹ fún mi, tó sì ti yí igbe ayé mi padà sí rere. Mo ti dàgbà sì nínú ọgbọ́n, òye àti ìrírí, mo sì ti di obìnrin tó ní òye sii".
"Koda, ìrírí tó dára julọ fún ẹ̀dá ni ìgbéyàwó jẹ nítorí ó tí yí idamọ mi padà. Mo ti di 'Mummy Ire', ìgbéyàwó mi sì ọlọ́gbọ́n ọkùnrin tí mú àyípadà bá mi, mo sì ti kúrò ní Toyin tí àwọn èèyàn mọ tẹ́lẹ̀."
Bẹẹ bá gbàgbé, ọjọ́ kẹrin oṣù keje ọdún 2019 ni Toyin Abraham àti ọkọ̀ rẹ, Kolawole Ajeyemi ṣe ayẹyẹ ìdána n'ilu Ibadan, tí ọba òkè si fi ọmọkùnrin kan lanti lanti tá wọn lọrẹ, ti orúkọ rẹ ń jẹ Ire.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí eto iranwọ to ṣe lásìkò igbele koronafairọọsi yìí, Toyin Abraham ni òun ti pín owó àti èròjà oúnjẹ fún àwọn olólùfẹ́ òun ti oun mọ káàkiri ìlú Èkó, ibadan, Ogbomoso, Ilorin, Kano àti ní Ìpínlẹ̀ Ogun, ní ìwọ̀nba tí agbára òun ka.
Toyin sọ síwájú pé, òun rí pe Ọlọ́run ló ń fi agbára rẹ hàn wá nípa àrùn Covid-19 yìí, nítorí ohun gbogbo kò leè rí bíi ti àtẹ̀yìnwá mọ, lẹ́yìn ti àrùn náà bá kasẹ nilẹ.
"Lásìkò yìí, ọna bí ẹnì kọ̀ọ̀kan wá kò ṣe ní kú là ń ṣàn, bí a ṣe ye là ń wá, a kò lè owó mọ rárá àbí bá ti tà sinima wá, kódà, èmi àti ọkọ mi kan gbé mọto wa kalẹ ni, lai le lọ síbi kankan, ẹ rí pé èyí lágbára gan ni."
Lati: BBC
No comments:
Post a Comment