Ọjọ́ gbogbo ni wọn pé táwọn igara ọlọ́ṣà, ṣùgbọ́n síbẹ̀, ọjọ́ kan ṣoṣo báyìí náà ni wọ́n pè tí olohun. Wọnyi gan án lọrọ tí wọn loo lọ nibamu pẹ̀lú bí àṣírí ọkàn lára àwọn ọga ọlọpaa tí wọn loo gbajumọ dáadáa n'ilu Eko, ẹni tí wọn loo fẹran láti máa lu àwọn aráàlú ni jìbìtì.
Taloju Matins ni wọn pé orúkọ ọga ọlọpaa náà, agbegbe Ọkọta nijọba ìbílẹ̀ Oṣodi/Isọlọ, ipinlẹ náà lo tí ń ṣíṣẹ.
Ọjọ́ Ẹti tí í ṣe Fraide tó kọjá yìí laṣiri Taloju Martins tú síta nínú fọ́nrán rẹ kan tí wọn gbé sórí ìkànnì ayélujára níbi wọn lo tí ń gba owó riba lọ́wọ́ awakọ kan kò tó o fi silẹ.
Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì {40,000} náírà là gbọ pé Taloju gba lọ́wọ́ awakọ kan tó lugbadi òfin kònilegbele, kò tó o fi mọto rẹ silẹ.
AWIKONKO gbọ pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta {50,000} náírà tí Taloju béèrè lọ́wọ́ láti awakọ náà kò tó o di pé ó gbà ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bẹ̀.
Awakọ náà ni wọn loo fi fóònù rẹ yà fọ́nrán níbi tí Taloju tí ń gba owó náà lọ́wọ́ ẹ, tí ó sì fi ranṣẹ sórí ìkànnì ayélujára kí gbogbo agbaye lè rí í.
Ọkàn lára àwọn gbajumọ amuludun lorilẹ-ede yìí là gbọ pé fọ́nrán náà tẹ lọ́wọ́, toun náà sì gbé sórí ìkànnì ayélujára rẹ, èyí gan án ní wọn loo jẹ́ kí fọ́nrán náà tún tètè àwọn tó yẹ kó tẹ lọ́wọ́.
Alukoro fáwọn ọlọpaa ipinlẹ Eko, Bala Elkana fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, ó sì jẹ kò di mímọ̀ pé owó tí tẹ ọlọpaa náà, tó sì ti ń kawọ pọyin rojọ.
No comments:
Post a Comment