ỌWỌ FIJILANTE TẸ BUHARI, IRUN ONÍRUN LÓ Ń TA F'ÁWỌN BABALAWO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, April 7, 2020

ỌWỌ FIJILANTE TẸ BUHARI, IRUN ONÍRUN LÓ Ń TA F'ÁWỌN BABALAWO


Ṣikun báyìí lọ́wọ́ àwọn fijilante tijọba apapọ, ìyẹn  Vigilante Group of Nigeria, VGN nipinlẹ Ogun tẹ gendekunrin kan tí wọn pé orúkọ rẹ ni Aminu Buhari tí wọn ní kó niṣẹ méjì ju kò máa tá irun onírun fáwọn babaláwo láti fi ṣoogun owó lọ. 

AWIKONKO gbọ pé ọjọ Àìkú, ìyẹn Sande ijẹta lọ́wọ́ tẹ Buhari lágbègbè Kutọ n'ilu Abẹ́òkúta ni nnkan bí aago mọkanla àárọ̀ lásìkò táwọn èèyàn wa ninu ile wọn fún tí konilegbele tó ń lọ lọ́wọ́. 

Asiko ti wọn ni Bahuri àti ọrẹ rẹ tòun ti na pápá bora ni wọn fura si wọn, tí wọn sì dá wọn dúró láti béèrè ibi tí wọn ń lọ. Wọn ní bí ọrẹ Buhari ṣe rí àwọn fijilante náà tí Alimi Sọdiiki lewaju wọn lo tí bá ẹsẹ rẹ sọ̀rọ̀, èyí ló sì jẹ ki wọn fura pé kí í ṣojú lásán.

Ìdí re e tí wọn fi gba baagi tí Buhari gbé dání, nínú ẹ sì ni wọn ti rí oríṣiríṣi irun àwọn obìnrin, tó lòun fẹ ẹ lọ tá fáwọn babaláwo láti fi ṣoogun owó.

Nigba tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, Ọga agba fijilante, Ọlanrewaju Nureni Adededoyin sọ pe awọn ti mu afurasi naa lọ si teṣan awọn ọlọpaa to wa ni Ibara, ti iwadii si n tẹ siwaju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI