Ìjọba ipinlẹ Cross-River ti sọ pé kí òṣìṣẹ́ eleto ìlera yòówù tó bá wọ ipinlẹ náà wá yóò jẹ ìyan rẹ n'iṣu, torí pé ṣe làwọn yóò mú-un so láti jẹ kò wá ní igbele àyẹ̀wò tipátipá, ìyẹn quarantine.
F'awọn to bá mọ bí nnkan ṣe ń lọ dáadáa nípa àrùn aṣekupani tí kò gboogun tó ń dá gbogbo agbaye riboribo, ìyẹn Covid-19 tí wọn tún ń pè ní koronafairọọsi, pàápàá lorilẹ-ede Nàìjíríà, wọn a mọ pe ipinlẹ Cross-River wá lára àwọn ipinlẹ méjì àrùn náà kò ti í jẹyọ.
Àná tí í ṣe Wẹside ni kọmiṣanna feto ìlera n'ipinlẹ náà, Dọkita Betta Edu kéde síta wí pé àwọn kò ní í gba kí ìjọba àpapọ̀ gbé ru wọn láti ẹyin lórí ọ̀rọ̀ Covid-19 náà.
Dọkita Edu nígbà tó ń bù ẹnu atẹ lu ọwọ tijọba àpapọ̀ fi mú ọ̀rọ̀ àrùn náà lo tí sọ pé afi kijọba ronú ọ̀nà mi-in láti dẹ́kun itankalẹ àrùn náà, èyí tó yàtọ̀ gedegbe sì ọwọ tí wọn fi ń mú-un.
Ó tún sọ pé àwọn kò ṣetan láti gba òṣìṣẹ́ eleto ìlera kankan lálejò n'ipinlẹ náà lásìkò yìí, àti pé òṣìṣẹ́ eleto ìlera, ìyẹn NCDC tó bá wọ ipinlẹ náà wá làwọn yóò ti mọle fún àyẹ̀wò, ìyẹn quarantine.
Ṣáájú àsìkò yìí lọ́jọ́ Tuside ni àjọ NCDC tí sọ pé dandan ni ki àrùn koronafairọọsi tán káàkiri Nàìjíríà, nítorí náà làwọn ipinlẹ méjì yòókù ṣe gbọ́dọ̀ jáde síta láti kéde àwọn tó ní àrùn Covid-19.
Dọkita Edu ni ìjọba àpapọ̀ kò pèsè fún ipinlẹ tí kò ní àrùn náà, àwọn nǹkan tí wọn lé fi dènà itankalẹ rẹ, ìdí re e tó fi ní kí wọn fi wọn silẹ.
No comments:
Post a Comment