Ọmọ òfò gba a làwọn ara agbegbe Umudagu to wa n'ijọba ìbílẹ̀ Mbaitoli, ipinlẹ Imo ń pè baálé ilé kan, Johnbosco lórí bo ṣe sa màmá rẹ tó ti darúgbó, Pauline Ejiogu niṣakuṣa, to sì jẹ pe díẹ̀ lo kú kí màmá náà dagbere fàyè.
Ohun tó jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Johnbosco máa jẹ ìyàlẹ́nu fáwọn èèyàn, pàápàá àwọn tó wà lágbègbè yìí lọ́jọ́ náà ni bo tún ṣe dáná sún ara rẹ, pẹ̀lú màmá rẹ mọ inú ilé.
Àwọn tó wà nítòsí là gbọ pé wọn sáré ranṣẹ sì àwọn ọlọ́pàá, àtàwọn òṣìṣẹ́ ileeṣẹ panapana láti wá a pá iná naa.
Bí iná náà ṣe bẹ̀rẹ̀ si í jo làwọn èèyàn ti sáré lọ síbẹ̀, tí wọn sì já ilẹ̀kùn wọlé láti doola ẹmi Johnbosco àti màmá rẹ tó ti lè laadọrin ọdún.
Awuyewuye kan lo waye laarin Johnbosco ati mama rẹ, to fi di pe àwọn mejeeji bẹ̀rẹ̀ si i pariwo le ara wọn lori, ìyẹn lọ́jọ́ Ẹti, Fraide ọ̀sẹ̀ to kọjá.
Alukoro ileeṣẹ ọlọ́pàá, ó Orlando Ikeokwu jẹ́ kó yẹ wá pe nnkan bi aago mẹ́wàá kọjá ogun ìṣẹ́jú làwọn gba ipe laarọ ọjọ́ naa.
No comments:
Post a Comment