ỌGỌRUN BILIỌNU LA TI PÍN F'ÁWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ, KO SẸNI TI EBI Ń PA MỌ - LAI MOHAMMED - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, April 7, 2020

ỌGỌRUN BILIỌNU LA TI PÍN F'ÁWỌN ỌMỌ NÀÌJÍRÍÀ, KO SẸNI TI EBI Ń PA MỌ - LAI MOHAMMED


Minisita fún ọ̀rọ̀ ìròyìn lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Alaaji Lai Mohammed tí sọ pé kẹnikẹni má ṣe gba ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà gbọ rárá wí pé ebi ń pá wọn lásìkò konilegbele tó ń lọ lọ́wọ́ yìí.

Alaaji Lai Mohammed sọ pé owó tí kò dín ni biliọnu kan náírà làwọn tí pín fáwọn èèyàn káàkiri Nàìjíríà, pàápàá àwọn aláìní gẹ́gẹ́ bí owó ìranwọ láti ra oúnjẹ lásìkò kònilegbe yìí.

Látìgbà tijọba àpapọ̀ tí kéde konilegbele làwọn ọmọ Nàìjíríà tí gba orí gbogbo ìkànnì ayélujára lọ láti lọ kọ ọ sibẹ wí pé ó yẹ kijọba sẹranwọ fáwọn aráàlú. 

Lai Mohammed sọ pé irọ́ làwọn tó ń gbé ọ̀rọ̀ sórí ayélujára wí pé àwọn nílò iranlọwọ ìjọba lásìkò yìí, nítorí pé kò sẹni tí owó náà kò ti í tẹ lọ́wọ́.

Ṣùgbọ́n ṣá, ninu ìròyìn mi-ín ti Alaaji Lai Mohammed bàwọn oniroyin sọ lo tí sọ pé òun kò fìgbà kan rí sọ nnkan tó jọ bẹẹ rárá, àti pé àwọn ọ̀tá ìjọba lo wá nìdí ìròyìn ẹlẹjẹ náà.

O ni kẹnikẹni má ṣe gba ìròyìn náà gbọ rárá, nítorí pé ìṣòro kan tijọba ṣí ń gbajumọ báyìí ni ti aarun àṣekupani tí Coronavirus tó ń jà káàkiri àgbáyé. 

4 comments:

  1. eni tii Oni Ile epo ti owo re ko wa le oni lati ri be kojiya kokan ri o see ogun owo ni etun wadi e daada

    ReplyDelete
  2. Olohun oba asanwon lesan to tosiwon

    ReplyDelete
  3. E jo eba wa so fun awon ijoba was pe eto ounje to won se yen ku die kato, oun to o ye ki eyan merin pin ni community ni won ni ki a wa bi ile adota pin bawo la se fe pin jare ki won se atunse o

    ReplyDelete
  4. Ounje ti awon ijoba pin yen ku die ka to, ounje toye ko to si eyan merin ni won pin fun eyan adota, ki won se atunse o,

    ReplyDelete

PÍN-IN KÁÀKIRI